Sunday n gbeja aburo ẹ, lo ba gun alajọgbele wọn nigo pa l’Oṣodi

Faith Adebọla, Eko

Ọgbẹni Chibuike Nwanne, ẹni ọdun mẹtalelogoji, to ṣegbeyawo lọdun to kọja yii, tiyawo ẹ ṣi wa ninu oyun ti doloogbe o. Sunday Amaefula ni wọn lo gun un lọbẹ pa lọjọ Aje, Mọnde yii, wọn lo fẹẹ gbeja aburo ẹ ni.

Nnkan bii aago kan aabọ oru ọjọ naa niṣẹlẹ ibanujẹ naa waye, wọn ni ko ju bii wakati meji aabọ toloogbe naa atiyawo ẹ ṣẹṣẹ ti pati kan de ni, nija ọhun bẹrẹ nile wọn to wa l’Ojule kẹjọ, Opopona Akpaku, ni Mafoluku, Oṣodi, nipinlẹ Eko.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Eko, DSP Olumuyiwa Adejọbi, ṣalaye ninu atẹjade to fi sọwọ s’ALAROYE pe alajọgbele ni oloogbe yii ati Sunday Amaefula, pẹlu aburo Sunday kan, Ifeanyi Emmanuel.

Wọn ni ki ọkọọyawo naa too jade lọ si pati lọsan-an ọjọ Aiku, Sannde, to ṣaaju ọjọ iṣẹlẹ yii loun ati Ifeanyi ti ṣe gbolohun asọ kan ninu ile ọhun, wọn si bu ara wọn gidi.

Ẹjọ ija yii la gbọ pe Ifeanyi ro fun ẹgbọn ẹ nigba tiyẹn dari de, lọkunrin naa ba gẹgun de Chibuike, pe oun aa kọ ọ lọgbọn. Ko si pẹ ti Chibuike wọle loootọ ti ẹgbọn to fẹẹ gbeja aburo e yii fi tun fija pẹẹta pẹlu oloogbe naa.

Wọn ni pẹlu ibinu lafurasi ọdaran naa fi sare fa igo kan yọ, o pa a mọlẹ, lo ba da akufọ igo ọhun de ẹni to n ba ja latẹyin, bẹẹ loloogbe naa mudi lọọlẹ, wọn gbe e digbadigba lati du ẹmi, ṣugbọn o ti ku ki wọn too de ileewosan. Ni wọn ba lọọ fọrọ naa to awọn ọlọpaa teṣan Makinde, l’Oṣodi, leti.

Wọn ti waa fi pampẹ ofin gbe Sunday, wọn si ti fi i ṣọwọ sọdọ awọn ọtẹlẹmuyẹ ni Panti, Yaba.

 

Leave a Reply