T B Joshua wọ kaa ilẹ lọ, Akeredolu, Sanwo-Olu atawọn nla nla ṣẹyẹ ikẹyin fun un

Faith Adebọla, Eko

 Bi ẹsẹ ko ṣe gbero ni gbagede ati ayika ṣọọṣi Synagogue Church of All Nations (SCOAN) lọjọ Furaidee, ọjọ Ẹti, bẹẹ lomije n pe omije ran niṣẹ nibi isinku oludasilẹ ṣọọṣi ọhun, Wolii Temitọpẹ Balogun Joshua, to doloogbe lọjọ karun-un, oṣu kẹfa, ọdun yii.

Ṣe ọjọ iku laa d’ere, bamubamu lawọn olubanikẹdun, awọn ọmọ ijọ SCOAN, awọn aladuugbo atawọn mọlẹbi oloogbe kun tinu tode ṣọọṣi gagara naa, eyi ti wọn lo maa n gba to ẹgbẹrun mẹẹẹdogun lẹẹkan ṣoṣo, sibẹ ọpọ ni ko raaye wọle to jẹ ita fẹnsi naa ni wọn ti n fi ẹdun ọkan wọn han, ti wọn si n dagbere fun T B Joshua bi wọn ṣe n sin in.

Bo tilẹ jẹ pe wẹliwẹli ojo ko dawọ duro titi ti wọn fi sinku naa, sibẹ, awọn eeyan duro sinu ojo ọhun, iṣẹ aṣelaagun si lawọn ọlọpaa, awọn ṣọja, awọn oṣiṣẹ LASTMA ati awọn Sifu Difẹnsi, yatọ sawọn oṣiṣẹ ṣọọṣi naa ṣe lati maa dari awọn ero ati ọkọ, ati lati pese aabo lagbegbe naa.

Awọn eeyan nla nla, latori awọn aṣaaju ẹsin bii tiẹ, awọn oludasilẹ ijọ, awọn oloṣelu ati awọn lọgaalọgaa ẹgbẹ alaaanu kari aye lo pesẹ sibi ẹyẹ ikẹyin ti wọn ṣe fun gbajugbaja ajihinrere to wọ kaa ilẹ lọ yii.

Lara awọn eeyan wa nibi ayẹyẹ naa ni gomina ipinlẹ Ondo, Arakunrin Oluwarotimi Akeredolu, Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu, ẹni ti Kọmiṣanna lori ọrọ ile, Ọmọọba Ọlanrewaju Elegushi, ṣoju fun, ati Ayaba Ọọni ti Ile-Ifẹ, Olori Naomi Adeyẹye, pẹlu awọn ọnarebu aṣoju-ṣofin ati awọn alaga ijọba ibilẹ ipinlẹ Eko kan.

Leave a Reply