Ta lo maa gba ife ẹyẹ AFCON laarin Nigeria ati Cote D’Ivore

Faith Adebọla

O ti ṣẹlẹ! Gbẹgẹdẹ fẹẹ gbina! Bi ohun kan ba wa to maa n mu ki awọn awọn ọmọ Naijiria wa niṣọkan, ki ero wọn si papọ lasiko kan naa, bi asiko kan ba si wa ti ọpọ awọn ọdọ maa n gbagbe gbogbo idaniyan ati ipenija wọn, ti wọn yoo maa sọrọ kan naa pẹlu afojusun kan naa, idije ere bọọlu alafẹsẹgba bii iru eyi to n lọ lọwọ lorileede Cote D’Ivore yii ni.

Oni, ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kọkanla, oṣu Keji, iyẹn oṣu Fẹbuari, ọdun 2024 yii, ni eruku yoo sọ lala, ni papa iṣere Alassane Ouattara Olympic Stadium ọlọpọ ero to wa niluu Abijan. Ibẹ ni ẹgbẹ agbabọọlu to n ṣoju orileede Naijiria, Super Eagles, yoo ti wa a ko pẹlu ẹgbẹ agbabọọlu ti Cote D’Ivore ni nnkan bii aago mẹsan-an aṣalẹ ọjọ Sannde yii. Ifẹsẹwọnsẹ yii ni yoo si jẹ aṣekagba, tawọn oloyinbo n pe ni final, fun idije ife ẹyẹ ẹgbẹ agbabọọlu to peregede ju lọ nilẹ Africa, ife ẹyẹ AFCON.

Ẹẹmẹta ọtọọtọ ni Naijiria ti gba ife ẹyẹ yii ri, latigba ti wọn ti bẹrẹ lọdun 1957. Green Eagles ni wọn n pe ẹgbẹ agbabọọlu to ṣoju Naijiria ti wọn si gba ife naa fun igba akọkọ lọdun 1980, ilu Eko, lorileede Naijiria ni ifẹsẹwọnsẹ igba naa ti waye. Bẹẹ ni Super Eagles tun gbafe ọhun lọdun 1994 lorileede Tunisia ati ni 2013 lorileede South Africa.

Ti Naijiria ba tun gba a laṣalẹ ọjọ Sannde yii fun igba kẹrin, wọn yoo fi jọ orileede Ghana, tawọn naa gba kọọbu ọhun lẹẹmẹrin niyẹn.

Ni ti orileede Cote D’Ivore, eemeji pere ni wọn ṣi gba ife naa, iyẹn lọdun 1992 lorileede Senegal ati lọdun 2015 lorileede Equitorial Guinea, bi wọn ba jawe olubori laṣalẹ yii, wọn yoo ba Naijiria dọgba gẹgẹ bii orileede gbafe ọhun lẹẹmẹta, eyi ni yoo si jẹ igba akọkọ ti wọn maa gbalejo idije naa lorileede wọn ti wọn yoo si tun gbafe. Ọdun 1984 ti idije ọhun kọkọ waye lorileede naa, wọn o rin jinna rara ti wọn fi fidi rẹmi, ti wọn si di ero iworan titi tidije naa fi pari. O daju pe wọn o tun ni i fẹ ki eyi ṣẹlẹ si wọn, tori bẹẹ, o ṣee ṣe ki eegun wọn kan lakanṣe ninu aṣekagba toni-in.

Amọ bo ba jẹ ti iriri ninu gbigba bọọlu de ipele aṣekagba idije AFCON yii ni, ọga ni kan-un laarin okuta, olokiti bii ọbọ ko si ni tọrọ Naijiria, ẹẹmeje ọtọọtọ ni ẹgbẹ agbabọọlu Naijiria ti de ipele aṣekagba bii eyi, toni yii ni yoo jẹ ẹlẹẹkẹjọ, bo tilẹ jẹ pe ẹẹmẹta ni wọn gbe ife lọ. 

Ohun mi-in ti yoo tun ṣara-ọtọ loni-in ni ti ero rẹpẹtẹ ti yoo kun papa iṣere naa fọfọ. Bo tilẹ jẹ pe ẹgbẹrun lọna ọgọta iye ero ti wọn kọ sitediọmu naa fun, o ṣee ṣe ko kun akunfaya latari awọn ọmọ orileede Cote D’Ivore ti wọn maa waa ṣe koriya fun ẹgbẹ agbabọọlu wọn, yatọ si awọn alejo pataki atawọn aṣoju ajọ bọọlu agbaye, FIFA, ti wọn yoo wa nikalẹ. Bọọlu afẹmigba ni yoo si jẹ fun orileede naa.

Yatọ si eyi, ọkọọkan awọn alaṣẹ orileede mejeeji ni wọn ti ṣeleri owo ati ẹbun to joju ni gbese gidi fun awọn agbabọọlu wọn ti wọn ba fi le ṣaṣeyọri ifẹsẹwọnsẹ naa.

Amọ ṣa o, ọpọ eeyan lo n sọ pe bo ti wu ki idije yii gbona janjan to, orileede Naijiria ni yoo bori, tori ninu ifẹsẹwọnsẹ mẹfa to kọja, eemeji pere ni awọn alatako wọn ṣi gba bọọlu sawọn wọn.

Ohun mi-in tun ni ti amule Super Eagles, iyẹn Stanley Nwabali, to n mule fun ẹgbẹ agbabọọlu Chippa United lorileede South Africa ṣaaju idije yii, ọkunrin naa ti di ijaya fawọn ẹlẹsẹ ayo lori papa, ọkan rẹ si maa n balẹ lati gbegi dina fun bọọlu to ba fẹẹ wọ awọn, pọnkan lo maa n han wọn, eyi si tubọ fi Naijiria lọkan balẹ.

Ninu ifẹsẹwọnsẹ mẹfa ṣaaju asiko yii, bọọlu meje ni Naijiria ti gba sawọn, nigba ti Cote D’Ivore gba mẹfa wọle. Naijiria tun ni ọpọ awọn ẹlẹsẹ ayo bii Victor Osimien, bo tilẹ jẹ pe ami ayo kan lo ṣi gba sawọn, amọ gbogbo idije ni irawọ rẹ ti n tan bo ṣe n ran awọn ẹlẹgbẹ rẹ lọwọ, bẹẹ ni Ademọla Lookman, Samuel Chukwueze ati Kelechi Iheanaco, ti wọn pawọpọ fẹyin South Africa janlẹ l’Ọjọruu, Wẹsidee to kọja.

Amọ ṣe Cote D’Ivore yoo sọ fun Naijiria pe ibi ti wọn foju si ọna ko gbabẹ, ti wọn yoo si powe fun wọn pe kaka ki akere ma dun ọbẹ, tapa-titan lo ma a run si i ni? Ta ni yoo fagba han ẹni keji? Ta ni yoo dade ẹgbẹ agbabọọlu to peregede, to fi gbọrọ jẹka ju lọ nilẹ Afrika lọdun yii? Ipade di ilu Abijan, laṣalẹ oni.

CAPTION

Leave a Reply