Bi Arakunrin Rotimi Akeredolu ti yoo tun du ipo gomina lorukọ ẹgbẹ APC ninu idibo oṣu to n bọ yii ni ipinlẹ Ondo ti n pariwo si awọn agbofinro leti pe awọn tọọgi ni PDP n lo lati maa fi dẹruba awọn eeyan awọn kaakiri, bẹẹ naa ni Ọgbẹni Eyitayọ Jẹgẹdẹ ti yoo du ipo naa lorukọ PDP n pariwo pe awọn tọọgi APC fẹẹ ṣe awọn alatilẹyin awọn leṣe. Eyi lawọn araalu ṣe beere pe ta lo n to tọọgi gan-an ninu Akeredolu ati Jẹgẹdẹ.
Akeredolu funrarẹ lo pe awọn agbofinro gbogbo ni ipinlẹ Ondo pe ki wọn kilọ fawọn aṣaaju ati ọmọ ẹgbe PDP gbogbo ki wọn yee lo tọọgi lati kọlu awon ọmọ APC mọ o. Gomina naa ni nitori ibo to n bọ, awọn PDP ko ni iṣẹ meji ti wọn n ṣe mọ ju ki wọn maa ko tọọgi kiri lati fi da rogbodiyan silẹ, ti wọn yoo si maa pa awọn eeyan awọn lara. Richard Ọlabọde, agbẹnusọ igbimọ to n ṣeto ipolongo ibo fun Akeredolu, to sọro naa lorukọ Gomina yii ni ki awọn agbofinro tete kilọ fawọn PDP o.
Ṣugbon lẹsẹkẹsẹ ni Jẹgẹdẹ ti da ọrọ naa pada. Agbẹnusọ fun eto ipolongo tiwọn naa, Gbenga Akinmoyo, loun naa fi ọrọ si lẹnu. O ni ko si ootọ kan ninu ọrọ to tẹnu Akeredolu ati awọn eeyan rẹ jade, pe bi ẹni kan ba wa to yẹ ki awọn agbofinro kilọ fun, awọn APC yii ni, nitori ni gbogbo igba ni awọn aṣaaju wọn maa n kiri, ti wọn si n leri pe awọn yoo ṣe awọn aṣaaju PDP yoowu ti awọn ba ti ri leṣe.
Ohun to n ko awọn araalu lominu si ree, nitori bi agbọ́n ti n sẹ́, bẹẹ ni olóko n sẹ, oju olóko lo si lo wu kùlùbù-kulubu yii. PDP lawọn ko lo tọọgi, bẹẹ ni APC lawọn naa ko ni tọọgi, awọn tọọgi ko si yee da awọn oloṣelu Ondo laamu, nitori ibo gomina to n bọ yii naa si ni. Ta lo waa ni awọn tọọgi ti won n kiri igboro l’Ondo yii o.