Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ondo ti wọ ọkunrin kan, Ọlayiwọla Taofik, lọ sile-ẹjọ Majisireeti kan niluu Akurẹ lori ẹsun pe o lu Godwin Ọlayẹni, ni jibiti miliọnu mẹẹẹdọgbọn naira (N25m).
Visa, iyẹn iwe irinna siluu oyinbo, ni Taofik fi lu Ọlayẹni ni owo to fẹẹ to miliọnu mẹẹẹdọgbọn naira ọhun (N24, 750m). O loun yoo ba a ṣeto bi iyawọ atawọn ọmọ ẹ mejeeji yoo ṣe dero ilu oyinbo.
Ẹsun onikoko meji ni wọn ka si ọkunrin yii lẹsẹ, iyẹn ole jija ati jibiti, nibẹ naa lo si ti sọ pe oun ko jẹbi rara.
Ọlọpaa to duro gẹgẹ bii olupẹjọ, Adeoye Adeṣẹgun, sọ ọ nile-ẹjọ pe laarin oṣu kẹfa, ọdun 2018, si oṣu kẹjila, ọdun 2019, lagbegbe kan to n jẹ Orita-Obele Estate, niluu Akurẹ, nipinlẹ Ondo, ni Taofeek ti daran ọhun.
O ni ọgbọn alumọkọrọyi lo fi gba owo olowo ọhun, to si fi n ṣararindin ni tiẹ, ati pe iwa rẹ yii ni ijiya labẹ ofin ipinlẹ Ondo, ti ọdun 2006.
Aarẹ ile-ẹjọ Majisireeti ọhun, Ọgbẹni Ọlanipẹkun Mayọmi, ti fun ọkunrin ti wọn fẹsun kan yii ni beeli pẹlu miliọnu kan atawọn oniduuro meji ti wọn gbọdọ maa gbe ni adugbo ibi ti ile-ẹjọ ohun wa.
Ọjọ kẹrinla, osu kejila, ọdun yii, ni igbẹjọ yoo maa tẹsiwaju.