Olori ọja Aswani, l’Ekoo, Oloye Toareed Farounbi, ẹni tawọn eeyan tun mọ si Baba Alado, atawọn eeyan mẹfa kan ni ijọba apapọ ti wọ lọ sile-ẹjọ lori ẹsun pe wọn mọ bi awọn eeyan meji kan ṣe ku.
Ninu ẹsun koko mẹta ti wọn fi kan baba naa niwaju Adajọ Muslim Hassan nile-ẹjọ giga kan l’Ekoo, ni wọn ti sọ pe baba naa gbimọ pọ pẹlu awọn mẹfa mi-in, bẹẹ ni wọn tun lọwọ si iwa idaluru, eyi to ṣokunfa bi awọn eeyan meji kan, Debọ Olohunyọ ati Chibuzor Daniel, ṣe ku.
Ibi kan ti wọn pe ni White Sand, lagbegbe Ishẹri-Ọṣun, nipinlẹ Eko, ni wọn sọ pe wọn pa awọn eeyan ọhun si lọjọ kọkandinlogun, oṣu kẹta, ọdun to kọja.
Yatọ si eyi, wọn ni ọpọlọpọ dukia lawọn eeyan ti wọn ko wa sile-ẹjọ yii bajẹ lasiko naa, eyi to lodi si ofin idaluru tọdun 2013.
Baba Alado atawọn ti wọn jọ fẹsun kan ni: Alhaji Oluṣẹgun Akinde, ẹni tawọn eeyan tun mọ si Echo, Ayọkunle Fakiyesi, Idowu Akinde, Musiliu Ọladẹjọ, Lekan Matthew ati Adeleke Akindeji.
Lọjọ Aje, Mọnde, to yẹ ki igbẹjọ tun waye lori ọrọ ọhun, Lekan Mathew nikan lo yọju ninu gbogbo awọn ti wọn fẹsun kan yii, eyi gan-an lo fa a ti wọn ko fi le tẹsiwaju lọjọ naa. Olupẹjọ, A. K. Alilu, sọ fun adajọ pe latigba ti wọn ti fun wọn ni beeli, Lekan Matthew nikan lo yọju.
Loju ẹsẹ naa ni agbẹjọro awọn eeyan ti wọn fẹsun kan yii, M.B. Jimoh-Akogun, ti fi da ile-ẹjọ loju pe awọn eeyan oun ko sa lọ o, ati pe ohun ti wọn lero ni pe ọjọ kẹfa, oṣu kejila, ni igbẹjọ yoo waye, wọn ko mọ pe ọjọ Aje, Mọnde, ̀ọgbọnjọ, oṣu kọkanla, ni.
Nibẹ naa ni adajọ ti paṣẹ pe ki wọn lọọ fi Mathew to yọju lọjọ naa siọgba ẹwọn, nigba ti igbẹjọ mi-in yoo tun waye lọjọ kejidinlogun, oṣu kin-in-ni, ọdun 2021.