Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Adajọ ile-ẹjọ Majisreeti kan niluu Oṣogbo ti paṣẹ pe ki wọn lọọ fi awọn eeyan mẹjọ ti wọn fẹsun kan pe wọn fa wahala laafin ọba ilu Ikire pamọ sọgba ẹwọn.
Awọn olujẹjọ mẹjẹẹjọ naa ni Akeem Ọkẹowo, Hammed Rafiu, Lakin Oyetade, Ọkẹowo Saheed, Ibrahim Musiliu, Ahmed Sunmonu, Kareem Kamọrudeen ati Kọlawọle Ọpẹyẹmi.
Inspẹkitọ Elisha Oluṣẹgun to jẹ agbefọba sọ fun kootu pe laaarọ ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu kẹwaa, ọdun yii, ni wọn huwa naa laafin Akire, Ọba Ọlatunde Falabi.
O ṣalaye pe wọn jalẹkun wọnu aafin naa, wọn ba mọto Toyota Carina kan to ni nọmba AE 451 XXY to jẹ ti ọba naa jẹ, wọn si tun ba mọto Mazda to jẹ ti Oloye Falana Muritala jẹ lọjọ yii.
Awọn mẹjẹẹjọ ni wọn sọ pe awọn ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan wọn, agbẹjọro wọn, M. O. Oyeyinka, rọ ile-ẹjọ pe ki wọn da igbẹjọ naa pada siluu Ikire.
Majisreeti Modupẹ Awodele ni ki wọn ko awọn olujẹjọ lọ si ọgba ẹwọn ilu Ileefẹ, ki agbefọba gbe faili lọ si ẹka eto idajọ fun imọran.
Lẹyin naa lo da ẹjọ naa pada siluu Ikire, ti igbẹjọ yoo si bẹrẹ lọjọ kọkanlelogun, oṣu kejila, ọdun yii.