Ko ti i si ẹni to ti mọ iye awọn eeyan ti mọto ajagbe-ejo onigaasi kan pa daanu ninu ọja Bode niluu Ibadan bayii o. Nibi ti awọn ọlọja naa ti patẹ ọja wọn ni tirela naa ti ya bara, to si bẹrẹ si i gun ori awọn eeyan lọ. Ọpọ awọn mi-in ti ku loju ẹsẹ, ti awọn mi-in si kan lẹsẹ, ti awọn mi-in fara pa ti wọn ko le dide.
A ko ti i mọ ohun to fa idi ijamba naa, ohun ti awọn ọlọja funra wọn kan n pariwo ni pe ẹni kan ti riran si wọn lati bii ọjọ meloo sẹyin pe ki wọn fi ọjọ meje silẹ, ki wọn ma ṣi ọja Bode yii nitori ti wọn ba ṣi i, ohun aburu yoo ṣelẹ nibẹ.
Ambulaansi ti de, awọn panapana naa ti wa nibẹ ti wọn n gbe awọn oku yii, bẹẹ mi awon mi-in ṣi wa labẹ terrela n at won ko ti i le fa won yọ. Bi ọrọ naa ba ti jẹ gan-an, a o ṣalaye rẹ laipẹ.