Tẹru-tẹru la maa gbẹsẹ le ọkọ ajagbe to ba tun rin lọsan-an gangan l’Ekoo – Ijọba

Faith Adebọla, Eko

 

 

Ijọba ipinlẹ Eko ti koro oju si bawọn ọkọ ajagbe, tirela, ọkọ agbepo atawọn ọkọ to n pọn kọntena sẹyin ṣe n rufin irinna nipinlẹ naa, ti wọn si n da wahala silẹ lawọn oju ọna, wọn ni irufẹ ọkọ bẹẹ tọwọ awọn ba tẹ pe o n rin lojumọmọ, at’ọkọ at’ẹru inu rẹ lawọn maa gbẹsẹ le fun ọpọ oṣu tabi titi lae.

Kọmiṣanna feto irinna ati igbokegbodo ọkọ nipinlẹ Eko, Ọgbẹni Frederick Ọladẹinde, lo sọrọ yii lorukọ Gomina Babajide Sanwo-Olu, l’Ọjọruu, Wẹsidee, nibi ipade pataki kan to ṣe pẹlu awọn tọrọ kan l’Alausa, Ikẹja.

Ipade naa da lori bijọba ṣe fẹẹ kan an nipa fawọn awakọ atawọn to ni ọkọ ajagbe lati tẹle ‘Atunṣe Ofin Irinna Ipinlẹ Eko tọdun 2018’ (Lagos State Traffic Reform Law 2018). Ninu ofin naa ni wọn ti ka a leewọ fawọn ọkọ ajagbe wọnyi lati rin ọna eyikeyii lọsan-an, afi laarin aago mẹsan-an alẹ si aago mẹfa idaji nikan.

Ọladẹinde ni bawọn tọrọ kan ṣe n gun lagidi sofin yii wa lara ohun to n mu ki sun-kẹrẹ-fa-kẹrẹ lawọn oju ọna Eko di ọrọ abiku ti i sọ oloogun di eke, ti ijamba ọkọ ajagbe ati iṣẹlẹ ina ọmọ ọrara si n da ẹmi awọn eeyan legbodo.

O ni nibi tọrọ de yii, eyikeyii ọkọ ti wọn ba mu pe o rinna ṣaaju aago mẹsan-an alẹ, tabi lẹyin aago mẹfa owurọ, yoo wa lakata ijọba fun akoko gigun, awakọ ati ọlọkọ naa yoo si ri pipọn oju ijọba.

Yatọ siyẹn, o ni gbogbo ẹya ara ọkọ gbọdọ ṣiṣẹ, awọn ina to ba yẹ ko wa lara ọkọ ajagbe gbọdọ wa nibẹ, ki wọn si ṣiṣẹ bo ṣe yẹ, bẹẹ ni ere sisa wọn ko gbọdọ kọja ohun ti ofin la kalẹ.

Leave a Reply