Thomas atawọn ọrẹ ẹ ji mama ẹ gbe lati gbowo, lawọn ti wọn jọ ṣiṣẹ naa ba lu u ni jibiti

Faith Adebọla

Yooba bọ, wọn ni ọmọ ọsan ni i ko pompo ba iya rẹ, ọrọ yii lo jọra pẹlu afurasi ọdaran ẹni ọgbọn ọdun kan, Thomas Yau, tọwọ awọn agbofinro ṣẹṣẹ ba nipinlẹ Zamfara. Niṣe lọmọ yii ṣeto pẹlu awọn ọdaran ẹlẹgbẹ rẹ kan pe ki wọn ji mama to bi oun lọmọ gbe, ki wọn le gbowo nla lọwọ awọn mọlẹbi ẹ, wọn si ṣiṣẹ buruku ọhun, wọn gba miliọnu lọna ọgbọn Naira, amọ miliọnu kan pere lo pada kan Thomas ninu owo itusilẹ ti wọn gba ọhun.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, SP Mohammed Shehu, lo sọrọ yii di mimọ lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kejidinlogun, oṣu Keji yii, lasiko ti wọn n ṣafihan awọn afurasi ọdaran tọwọ ọlọpaa ṣẹṣẹ ba laipẹ yii.

Mohammed ni niṣe ni afurasi ọdaran to n gbe nijọba ibilẹ Makarfi, nipinlẹ Kaduna yii, gbimọ-pọ pẹlu awọn gende marun-un mi-in pe ki wọn waa ji iya oun gbe, o loun fẹ ki wọn ba oun gbowo lọwọ ẹ, tori oun mọ pe iya naa lowo lọwọ, wọn si jọọ ṣadehun pe ti wọn ba ti gbowo itusilẹ tan, wọn yoo jọ pin in bo ṣe yẹ.

Orukọ awọn marun-un yooku ti wọn jọ huwa ọdaju naa ni Abdulsamad Mohammed, ẹni ọdun marundinlaaadọta, Bello Abdullahi, ẹni ọdun marundinlogoji, Abubakar Namadi, ẹni ọgbọn ọdun, Suleiman Gabriel, ẹni ogun ọdun, ati Christopher Gabriel, ẹni ogun ọdun.

Wọn lo ti pẹ tawọn mẹfẹẹfa yii ti n ji-i-yan gbe gbowo lagbegbe naa, ko si sibi tọwọja eerin wọn ko to, bi wọn ṣe n ṣọṣẹ ni Zamfara, ni wọn n de Kaduna, Kano, Katsina ati Sokoto.

Olobo kan lo ta awọn ọlọpaa ti wọn fi dọdẹ wọn, ti wọn si ri wọn mu. Lasiko ti wọn n ṣewadii ni Thomas jẹwọ pe oun loun wa nidii bawọn ṣe lọọ ji mama to ṣe ọlọkọ oun wa saye gbe, tawọn si gba miliọnu lọna ọgbọn Naira, taati miliọnu, gẹgẹ bii owo itusilẹ. O ni iyalẹnu lo jẹ foun pe nigba ti wọn pin owo naa, miliọnu kan pere ni wọn lo kan oun nibẹ, miliọnu kan naa loun si gba. Wọn lo loun kabaamọ ohun toun ṣe.

Ṣa, Mohammed ni iwadii ṣi n tẹsiwaju lori awọn afurasi ọdaran wọnyi. O ni gbogbo wọn maa kawọ pọnyin rojọ niwaju adajọ tiwadii ba ti pari.

Leave a Reply