Ti Naijiria yoo ba goke agba, iṣẹ wa lọwọ adari atawọn ọmọlẹyin – Imaamu agba ilu Ọffa

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Imaamu Agba ilu Ọffa, Sheikh Muydeen Saliman, ti ke si awọn adari lorileede Naijiria lati yago fun iwa agabagebe, ki wọn si mọ pe oun to maa tan lọjọ kan ni ipo agbara ti wọn wa.

Bẹẹ lo ke si awọn araalu lati jẹ olootitọ ati ẹni to ni ifarajin si ohunkohun ti yoo mu idagbasoke ati itẹsiwaju ba orileede yii laayekaaye ti wọn ba wa.

Nibi eto idanilẹkọ Ramadan ti ọdun 2024 yii to ṣe niluu Ikire, nipinlẹ Ọṣun, eyi ti alakooso ajọ to n ri si igbokegbodo lori omi lorileede yii, Nigerian Inland Waterways Authority (NIWA), Alhaji Munirudeen Bọla Oyebamiji, gbe kalẹ ni Sheikh Saliman ti sọ pe ọpọ oloṣelu ni wọn n fi oju-aye ba ara wọn ṣe.

Nibi idanilẹkọọ ọhun ti wọn pe akori rẹ ni, ‘Iha ti Islam kọ si iwa agabagebe ati Ironupiwada’, ni baba naa ti pe gbogbo awọn adari lorileede yii nija lati gbe iwa titọ, idajọ ododo, aparo kan ko ga ju ọkan lọ ati ododo wọ bii ẹwu.

O ni wọn gbọdọ maa fi apẹẹrẹ rere lelẹ pẹlu ibẹru Ọlọrun, nitori iwa agabagebe ti ṣakoba to pọ fun idagbasoke awujọ wa, gbogbo awọn Musulumi ododo si gbọdọ gbogun ti i.

Ninu ọrọ tirẹ, Alhaji Oyebamiji ke si gbogbo awọn ọmọ Naijiria lati mọ pe ko si nnkan to le kọja adura, o ni ki wọn tubọ maa gbadura fun awọn adari atijọba orileede yii.

O ni Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu nilo ifọwọsowọpọ gbogbo eeyan lati le mu oniruuru erongba rere to ni fun orileede yii, to si ti dawọle ni ẹkajẹka, ṣẹ.

Oyebamiji, ẹni to lo akoko naa lati pin oriṣiiriṣii ounjẹ fun awọn eeyan ilu Ikire, Gbọngan, Ikoyi, Apomu, Orile-Owu ati bẹẹ bẹẹ lọ, sọ pe pẹlu afojusun ti Tinubu ni, laipẹ yii ni Naijiria yoo di apewaawo kaakiri agbaye.

Leave a Reply