Tinubu dangajia lati di aarẹ orileede yii-Ataọja Oṣogbo

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Oludije funpo aarẹ orileede yii ninu ẹgbẹ oṣelu APC, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu ti sọ pe ti ohun ba le lanfaani lati de ipo naa, oun yoo ri i daju pe iṣọkan wa laarin gbogbo ẹya to wa lorileede yii.

Nigba ti Tinubu gbe ipolongo ibo rẹ lọ si aafin Ataọja ti ilu Oṣogbo lọsan-an ọjọ Ẹti, Furaidee, lo sọ pe orileede yii nilo akinkanju ti yoo gbe e debi aṣeyọri.

Gomina ipinlẹ Eko tẹlẹ naa sọ pe oun ni oye kikun ninu siṣakoso awọn nnkan alumọọni, o ni amuyẹ yii ni ọpọlọpọ ri lara oun ti wọn fi sọ pe dandan ni ki oun dupo, oun si ti pinnu pe oun ko ni i ja awọn ọmọ orileede yii kulẹ rara.

O ni, “Emi ni ẹni naa to ni amuyẹ ti orileede yii nilo fun igbega, iṣọkan ati aluyọ, ki i ṣe ni Afrika nikan, bi ko ṣe ni gbogbo agbaye. Lẹyin ti mo ti ṣayẹwo iwe ofin ilẹ wa, mo beere lọwọ ara mi pe ta lo tun san ju mi lọ, idi niyẹn ti mo fi jade lati ba awọn eeyan sọrọ, mo si ti ṣetan lati sin orileede yii.

“Mo ti lọ kaakiri orileede yii, mo fi ara mi silẹ lati di aarẹ orileede Naijiria. Mo ti sọ fun Buhari nipa rẹ, mo sọ fun un pe mo ṣetan lati kẹsẹ bọ bata rẹ, ki i ṣe lati kan (break) ọmọ-ika ẹnikẹni. Mo sọ fun un pe mo fẹẹ sin orileede yii pẹlu ipa ti mo ni.

“A nilo ọpọlọpọ iṣẹ, eto ẹkọ to ye kooro fun awọn ọmọ wa, a nilo itẹsiwaju lorileede wa. A nilo ẹni ti yoo ṣe eleyii fun wa, o wa ninu orin orileede wa atijọ pe ‘loootọ a le yatọ sira ninu ede ati ẹya, ṣugbọn ara kan ni wa. A gbọdọ mọ pe ẹjẹ kan naa lo wa ninu iṣan wa lai fi ti ẹya ati igbagbọ ṣe.

“Ki i ṣe iṣẹ awọn to n gbẹ saare oku ni mo fẹẹ ṣe, ki i ṣe iṣẹ ere-sisa, ki i si ṣe iṣẹ ẹṣin gigun tabi iṣẹ birikila. Mo lọ sileewe lati kẹkọọ nipa iṣiro owo ati akoso. Mo fẹẹ ṣe iṣẹ to nilo ọpọlọ, ọgbọn ati arojinlẹ. Mo ṣetan lati ṣe ohun to tọ, iṣẹ ti mo fẹẹ ṣe ni lati gbe orileede yii goke agba.

Ninu esi tirẹ, Ataọja Oṣogbo, Ọba Jimoh Ọlanipẹkun, sọ pe asiko ti to fun iran Yoruba lati fi ohun ṣọkan lori ọrọ Tinubu nitori o dangajia lati di aarẹ orileede yii.

O ni gbogbo ilu Oṣogbo lo wa pẹlu Tinubu lori erongba rẹ yii, oun si mọ pe ko ni ja awọn ọmọ orileede yii ni tan-n-mọ-ọn.

Leave a Reply