Jọkẹ Amọri
Ajọ eleto idibo ilẹ wa ti kede oludije sipo aarẹ ẹgbẹ oṣelu APC, Aṣiwaju Bọla Tinubu gẹgẹ bii ẹni to jawe oluori ninu eto idibo sipo aarẹ to waye lọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Keji, ọdun yii.
Pẹlu ibo ti wọn di kaakiri orileede yii ati olu ilu ilẹ wa Abuja, gbogbo esi idibo naa fi han pe Tinubu lo ni ibo to pọ ju lọ.
Ibo to din diẹ ni miliọnu mẹsan-an (8,805, 420) lo ni, ibo to din diẹ ni miliọnu meji lo fi na alatako rẹ to wa nipo keji, Atiku Abubakar, ẹni to ni ibo miliọnu meje din diẹ (6,984, 290). nigba ti oludije ẹgbẹ Labour, Peter Obi wa ni ipo kẹta. Ibo to le diẹ ni miliọnu mẹfa (6, 093,962) loun ni.