Tinubu fi orukọ Masari ranṣẹ gẹgẹ bii igbakeji rẹ

Jọkẹ Amọri
Lati le ba ọjọ Ẹti, Furaidee, ti ajọ eleto idibo ilẹ wa, INEC, fun awọn ẹgbẹ oṣelu lati fa ẹni ti yoo ṣoju wọn lasiko eto idibo ti yoo waye ni ọdun to n bọ kalẹ, Aṣiwaju Bọla Tinubu to jẹ oludije fẹgbẹ APC ti fa Kabir Ibrahim Masari to wa lati ipinlẹ Katsina kalẹ gẹgẹ bii igbakeji rẹ. Bo tilẹ jẹ pe o ṣee ṣe ko ṣe ayipada si eleyii nigba ti anfaani ba ṣi silẹ lati paarọ orukọ oludije gẹgẹ bi iweeroyin Daily Trust ṣe fidi rẹ mulẹ.
ALAROYE gbọ pe wọn yoo pada yọ orukọ ọkunrin naa, ti wọn yoo si fi ti ẹlomi-in ti wọn ba fẹnu ko le lori si i lẹyin ti awọn alẹnulọrọ ninu ẹgbẹ naa ba fẹnu ko lori ẹni ti wọn fẹẹ fa kalẹ gẹgẹ bii igbakeji aarẹ ninu ẹgbẹ wọn.
A gbọ pe Tinubu yoo tun ṣepade pẹlu Buhari l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, lati fẹnu ọrọ jona lori eleyii. Wọn ni gomina ipinlẹ Borno tẹlẹ, Kashim Shetima, lo wu Tinubu lati fa kalẹ, ṣugbọn awọn gomina ilẹ Hausa ni wọn fun ni anfaani lati fa igbakeji kalẹ.
Ṣugbọn pẹlu bi nnkan ṣe n lọ, awọn agbegbe ilẹ Hausa mejeeji, iyẹn awọn ara Ariwa ati Aarin Gbungbun ni wọn n ja fitafita lati du ipo yii.
Ohun ti awọn eeyan ti n sọ ni pe o ṣee ṣe ki tikẹẹti ki aarẹ ati igbakeji jẹ Musulumi ṣakoba fẹgbẹ oṣelu APC ti wọn ba gbidanwo rẹ. Ṣugbọn bi nnkan ṣe n lọ, ko jọ pe awọn Hausa-Fulani yoo fẹẹ fi ipo igbakeji yii silẹ fun awọn eeyan Middle Belt to jẹ pe Onigbagbọ lo pọ ninu wọn.
Ko ti i sẹni to mọ bi wọn yoo ṣe gori afara ipenija yii ti ko fi ni i ṣakoba fun wọn lọdun to n bọ.

Leave a Reply