Jọkẹ Amọri
Lẹyin to ṣabẹwo si gomina ipinlẹ Niger, Abubakar Sanni Bello, nibi to ti beere fun atilẹyin gomina yii atawọn eeyan ipinlẹ Niger lori ipo aarẹ to fẹẹ du lo fun ijọba naa ni miliọnu lọna aadọta Naira lati fi ṣeranwọ fun awọn eeyan ti awọn afẹmisofo ṣakọlu si nipinlẹ naa.
Ile ijọba ipinlẹ Niger, ni Minna, ni gomina ti gba a lalejo l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọhun.
Lẹyin abẹwo naa lo gba ile aarẹ Naijiria lasiko ijọba ologun, Ibrahim Badamọsi Babangida lọ, nibi to ti lọọ beere fun atilẹyin ọkunrin naa lori ipo aarẹ to fẹẹ du.