Abdulsalami kilọ funjọba: Ẹ jawọ lori ẹkunwo epo bẹntiroolu ti ẹ n gbero latiṣe

Faith Adebọla

 Olori orileede wa laye ologun, Ajagun-fẹyinti Abdusalami Abubakar, ti kilọ funjọba pe ki wọn jawọ ninu erongba lati fi kun owo tawọn eeyan yoo maa ra jala epo bẹntiroolu, o ni wahala ati inira gidi lọrọ naa maa mu wa fawọn eeyan, oṣi ati iṣẹ yoo si pọ si i.

Abdulsalami sọrọ yii niluu Abuja l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, nigba to n sọrọ gẹgẹ bii olubanisọrọ pataki nibi apero kan tiweeroyin Daily Trust ṣeto rẹ.

Ọkunrin naa ni “lọwọlọwọ yii, nnkan bii miliọnu lọna ọgọrin awọn ọmọ orileede yii ni oṣi, iya ati iṣẹ n ba finra. Aito ounjẹ doju kọ orileede wa, ipenija arun Korona si tun da kun wahala ọhun.

Bijọba ba yọ afikun owo-ori epo bẹntiroolu kuro, ti nnkan naa si tun lewo si i, niṣe ni yoo sọ ọpọ ọmọ Naijiria sinu ebi, iṣẹ ati oṣi paraku, inira naa ko si ni i daa rara.

O rọ ijọba Buhari ki wọn ronu, ki wọn si wa awọn ọna mi-in ti wọn yoo fi pawo wọle labẹle, lai fi kun owo-epo.

Abdusalami tun ṣekilọ pe ọrọ eto idibo gbogbogboo to n bọ lọna lọdun 2023 yii gba ẹsọ pẹlẹ ati ọgbọn, nitori o le ṣakoba fun ajọṣe ati wiwa papọ orileede yii.

“Ẹ ṣakiyesi pe fun igba akọkọ, awọn gomina iha Guusu ati awọn gomina lati iha Ariwa orileede wa ti dojukọ ara wọn, kaluku lo n fẹ ki ipo aarẹ bọ sọdọ awọn ati agbegbe wọn.

“Idibo to n bọ yii gba pe ka simẹdọ gidi, ki ifẹ Naijiria si wa nipo akọkọ lọkan kaluku wa, ki orileede yii ma baa wo.

“Ẹ jẹ ka ranti pe yatọ sawọn ipenija ati idunkooko mọ ni to n koju Naijiria, ka wa lodidi ṣe koko, ba a si ṣe maa wa lodidi ṣe pataki.

Iṣọkan wa ati ba a ṣe pọ gbọdọ jẹ anfaani ati okun fun wa ni.”

Bẹẹ ni olori tẹlẹri naa sọ.

Leave a Reply