Agege ni Ridwan atawọn ọrẹ ẹ ti da Yusuf lọna, ni wọn ba gbowo ati foonu ẹ

Faith Adebọla, Eko

Ẹni ogun ọdun pere ni Ridwan Imran, ọmọọdun mejidinlogun si ni Abiọdun Lukman ati Isa Abdullahi ti wọn jọ n ṣiṣẹ, ṣugbọn iṣẹẹbi ni wọn n ṣe ni tiwọn, ibi ti wọn ti n ja awọn ero lole lọwọ ti ba wọn l’Agege, nipinlẹ Eko.

Gẹgẹ bi alaye ti Ọga agba ikọ ọlọpaa ayara-bii-aṣa RRS (Rapid Response Squard), CSP Ọlayinka Ẹgbẹyẹmi, ṣe ninu atẹjade kan to tẹ ALAROYE lọwọ, o ni Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, niṣẹlẹ naa waye.

Alaye ti ẹni tọrọ naa ṣẹlẹ si, Yusuf Ahmed, ṣe ni teṣan ọlọpaa ni pe ọkan ninu awọn kọsitọma oun lo pe oun fun iṣẹ kan lọwọ irọlẹ ọjọ naa, o si ko ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un naira (N100,000) foun lati fi ra awọn ẹya ara ọkọ Sienna toun fẹẹ ba a tunṣe lọjọ keji.

“Bi mo ṣe de gareeji ti wọn ti n wọ ọkọ Iṣẹri si Berger, o ti n lọ si bii aago mẹjọ aabọ alẹ nigba yẹn, Ridwan atawọn ọrẹ ẹ ni mo ri, wọn ni dandan ki n fun awọn lowo, ebi n pa awọn. Mo si bẹ wọn pe ko sowo lọwọ mi, tori owo mọto ati owo ti wọn ṣẹṣẹ ko fun mi nikan lo wa lapo mi.

“Ki n too mọ nnkan to n ṣẹlẹ, awọn janduku bii mẹfa ti yi mi po, niṣe ni wọn n tu jade nibi ti wọn sa pamọ si, ni mo ba fere ge e. Bi mo ṣe n sa lọ lawọn naa gba fi ya mi, mo n lọgun ‘ẹ gba mi o, ole, ole’, boya wọn aa pada lẹyin mi, ṣugbọn wọn o dẹyin.

“Wọn le mi lati gareeji yẹn de itosi papa iṣere Agege (Agege Stadium), ni wọn ba ti mi sinu gọta, wọn fọ igo mọ mi lori, wọn si gba gbogbo owo to wa lapo mi ati foonu mẹta. Mi o tiẹ mọ pe mo ṣi wa laaye tori ẹjẹ ti bo mi.”

Ẹgbẹyẹmi ni ariwo tọkunrin naa n pa lo jẹ kawọn eeyan kan ta ikọ RRS lolobo bi wọn ṣe n patiroolu agbegbe naa, ni wọn ba dọdẹ awọn afurasi ọlọṣa naa, wọn si ri mẹta mu ninu wọn.

O lawọn ṣi n wa awọn yooku, ṣugbọn wọn ti ri owo ati foonu ti wọn ji lọwọ Yusuf gba pada, wọn si ti taari awọn afurasi naa sakata awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ni Panti. Iwadii ti n lọ lori wọn.

Leave a Reply