Faith Adebọla, Eko
Idunnu ati ayọ lo han loju gbogbo ero rẹpẹtẹ to wa nibi ayẹyẹ ṣiṣi afara tuntun Pen-Cinema, to wa nikorita kan l’Agege, ti wọn ṣẹṣẹ kọ pari, ọjọ Ẹti, Furaidee yii, ni Gomina Babajide Sanwo-Olu tipinlẹ Eko ṣi afara naa, o ti di lilo faraalu bayii.
Tilu-tifọn layẹyẹ ọhun, wamuwamu si lẹsẹ awọn lọgaa-lọgaa ninu iṣakoso Sanwo-Olu ati lagbo oṣelu, pe sibi eto naa. Gomina ipinlẹ Eko nigba kan, to tun jẹ aṣaaju lẹgbẹ oṣelu APC, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, naa yọju sibi ayẹyẹ ọhun.
Nigba to n sọrọ nibi ayẹyẹ naa, Sanwo-Olu ni ọdun 2017 nijọba ipinlẹ Eko ti ronu ati kọ afara ọhun lati mu irọrun ba lilọ bibọ ọkọ, ati lati wa ojuutu si bi sun-kẹrẹ fa-kẹrẹ ṣe mu aifararọ wa fawọn eeyan agbegbe naa. O ni ireti wa pe biriiji yii maa mu ki lilọ bibọ ọkọ ja geere titi de awọn ọna Abule-Ẹgba, Agege-Ọja, Iyana-Ipaja, Iju-Iṣaga ati Ọgba lọ bẹẹ.
O ni ida ogun ninu ọgọrun-un ni ijọba ana ba iṣẹ de lori kikọ afara oni-kilomita kan aabọ (1.4 km) ọhun ki oun too bọ sori aleefa lọdun 2019.
Gomina tun gboṣuba fun kọngila to ṣiṣẹ naa, o ni ojulowo iṣẹ ni wọn ṣe, wọn si ṣe e doju ami, pẹlu bi ko ṣe si ajalu kan lasiko tiṣẹ n lọ lọwọ, ti wọn mu eto aabo lọkun-unkundun, ti wọn si ṣe gbogbo nnkan letoleto. O ni biriiji yii maa tubọ mu ki ọrọ aje ati kara-kata sunwọn si i, o si tun buyi kun ilu Eko.
Gomina waa kilọ pe kawọn awakọ ma ṣe tori bi ọna naa ṣe n yọ kuluulu, ki wọn maa tẹ ina atẹkanlẹ lai bikita. Bakan naa lo tun kilọ fawọn ọmọ ganfe pe abẹ biriiji naa ki i ṣe ile awọn amugbo, awọn o si ni i gba awọn ọlọja laaye lati gbe kanta ọja sibẹ rara.
Aṣiwaju Bọla Tinubu naa sọrọ nibi ayẹyẹ naa, o ni inu oun dun gan-an pe iṣakoso to wa lode yii ko pa awọn iṣẹ ode to ba nilẹ ti, niṣe lo n pari wọn.
Tinubu waa gba awọn ọdọ nimọran lati dẹkun biba awọn dukia ijọba jẹ lasiko ti wọn ba n fẹhonu han, o ni ki wọn kẹkọọ beeyan ṣe n sọrọ lati yanju aawọ nitubi inubi dipo didana sun awọn nnkan ini ijọba to n ṣanfaani fọpọlọpọ eeyan bii ti afara yii.
Olori ileegbimọ aṣofin Eko, Mudashiru Ọbasa, ati Olu tilu Agege, Ọba Kamilu Isiba. wa lara awọn eeyan pataki nibi ayẹyẹ naa.