Jọkẹ Amọri
Oludije funpo aarẹ lorukọ ẹgbẹ APC ninu eto idibo ọdun to n bọ, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, ti kede gomina ipinlẹ Borno tẹlẹ, Kashim Shetima, gẹgẹ bii igbakeji rẹ ti wọn yoo jọ dije dupo ninu eto oṣelu ọdun to n bọ.
Ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, ni Tinubu kede ọkunrin naa niluu Daura, nipinlẹ Katsina, lasiko to ṣabẹwo si Aarẹ ilẹ wa, Muhammadu Buhari.
Pẹlu ẹni ti wọn yan yii, o tumọ si pe Musulumi ni yoo dupo aarẹ ati igbakeji lorukọ ẹgbẹ APC.
Tẹ o ba gbagbe, lọjọ Abamẹta, Satide, opin ọsẹ to kọja yii ni Gomina ipinlẹ Kano, Abdullahi Kanduje, ti sọ pe Musulumi ni Tinubu yan gẹgẹ bii igbakeji rẹ ti wọn yoo jọ dupo aarẹ lọdun to n bọ.
Latari ipinu yii lo mu ki Ibrahim Masari, lati ipinlẹ Katsina, ti ẹgbẹ APC kọkọ fi orukọ rẹ ranṣẹ lati le ba gbedeke ti ajọ eleto idibo fun wọn nigba naa kọwe fipo silẹ.
Ọjọ Aiku, Sande ọsẹ yii ni iroyin gbe e pe ọkunrin naa ti kọwe fi ipo naa silẹ, o loun ko ṣe mọ. Eyi yoo fun ẹni ti wọn ṣẹṣẹ yan yii anfaani lati bọ si ipo naa.