Faith Adebọla
“Tinubu o ki i ṣe ọmọ Eko, ki i ṣọmọ Eko, mi o yọ ọ sọ. Ti wọn ba ni ta lo sọ bẹẹ, ẹ lemi ni. To ba lọmọ Isalẹ-Eko loun, ko darukọ ileewe to lọ, ibi to ti ka pamari ẹ da. Eko lemi wa, Opopona Evans, ni mo dagba si, Ojule karundinlogoji, Opopona Evans, ni ile baba agba wa wa. Community School, ni mo lọ. Mo gba bọọlu ni papa iṣere kan naa to wa n’Isalẹ-Eko, ibẹ ni gbogbo wa ti n gba bọọlu, ta a ti n ṣere. Bi gbogbo eeyan ṣe mọ mi niyẹn, ko sẹni to le jiyan ẹ.”
Agba-ọjẹ oloṣelu ilu Eko nni, Oloye Bọde George, to ti figba kan jẹ igbakeji alaga apapọ ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, lo la ọrọ yii mọlẹ laaarọ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹtala, oṣu Kejila, ọdun 2022 yii, nibi ifọrọwanilẹnuwo kan ti tẹlifiṣan Arise ṣe fun un.
Lasiko ifọrọwerọ naa ni wọn beere ọrọ nipa oludije funpo aarẹ ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu. Bọde George ni ẹni to maa wa nipo aṣaalu lorileede ko gbọdọ ni iwa aiṣootọ ati abosi lọwọ, o ni Tinubu ta ku, ko sootọ nipa ọmọ ibi toun jẹ gan-an, o ni niṣe lọkunrin naa n gọ sabẹ ika kan fawọn ọmọ Naijiria, bẹẹ ọpọ awọn nnkan nipa ẹ to yẹ kawọn ọmọ Naijiria to fẹẹ ṣakoso le lori mọ lo n daṣọ bo lori.
Alagba George tun sọ fakọroyin wa lori aago pe ọrọ to da ni loju ki i kọsẹ lete, o ni wọn ti mu oun deleewe ti Tinubu lọ ni kekere ẹ niluu Iragbiji, oun mọ’di tọkunrin naa ko fi le jade si gbangba, ko si sọ ootọ ọrọ faye gbọ, tori purọ n niyi, ẹtẹ ni i mu wa.
Akọroyin wa tun bi i lere boya ẹgbẹ oṣelu rẹ, PDP, yoo le yanju lọgbọ-lọgbọ aarin wọn ko too dọjọ idibo, ọkunrin ti wọn fi joye Atọna Oodua ilẹ Yoruba yii ni ko sohun ti ko ṣee yanju, o lọrọ ti o le ni, ṣugbọn awọn agbaagba ẹgbẹ PDP ni wọn o ti i ṣetan lati yanju ẹ, tori o yẹ ki wọn fi ohun ti i ṣe ti Kesari fun Kesari ni, igba yẹn lọrọ ọhun maa niyanju.
O lawọn eeyan ilẹ Yoruba ko ti i lanfaani ipo alaga apapọ latigba ti wọn ti da ẹgbẹ PDP silẹ, tori naa, lati le mu ki alaafia wa ninu ẹgbẹ, ojooro kankan o gbọdọ si, ki wọn lo ilana pin-in’re la-a-ire.