Jọkẹ Amọri
Gbogbo eeyan lo n garun lọtun-un losi, ti wọn si n wo raaraara, nigba ti awọn oludije funpo aarẹ n wọle si gbọngan ipade alaafia kan ti wọn ṣe International PConference Centre, niluu Abuja, ni Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹsan-an, ọdun yii, ti wọn ko si ri oludije sipo aarẹ lẹgbẹ APC, Asiwaju Bọla Tinubu. Niṣe ni awọn to ri fidio naa n beere pe nibo ni oludije funpo aarẹ ẹgbẹ oṣelu APC wa, iyẹn nigba ti wọn ri gbogbo awọn oludije ẹgbẹ oṣelu yooku ti wọn pe jọ siluu Abuja, nibi ti wọn ti kọwọ bọwe ofin tuntun lati gba alaafia laaye lasiko ipolongo ibo ọdun to n bọ.
O fẹrẹ jẹ pe Tinubu nikan ni igbakeji rẹ ṣoju fun laarin awọn ẹgbẹ oṣelu to gbajumọ ju lara awọn oludije nibi ipade alaafia ọhun.
Dipo ti Aṣiwaju iba fi wa, igbakeji rẹ, Kashim Shettima, lo ṣoju fun un. Bakan naa ni Alaga ẹgbẹ wọn, Abdullahi Adamu, ati adari ipolongo fun ẹgbẹ APC, to tun jẹ gomina ipinlẹ Plateau, Simon Lalong, ni wọn waa ṣoju ẹgbẹ APC nibi ipade ọhun.
Lara awọn oludije sipo aarẹ to tun wa nibi ipade naa ni Peter Obi ti ẹgbẹ Labour (LP), Ọmọyẹle Ṣoworẹ, Action Alliance (AA), Rabiu Kwakwanzo ti ẹgbẹ New Nigerian Peoples Party (NN[[), pẹlu awọn mi-in.
Bakan naa ni Alaaji Atiku Abubakar ti ẹgbẹ PDP ti ọgọọrọ awọn ọmọ ẹgbẹ naa bii Bukọla Saraki, Aminu Tambwal, alaga ẹgbẹ naa tẹlẹ, Secondus, atawọn oloye ẹgbẹ mi-in tele lọ sibẹ.
Lọsẹ to kọja yii ni wọn ni Tinubu lọ si ilu oyinbo, bo tilẹ jẹ pe ko sẹni to mọ ohun to tori rẹ lọ. Ṣugbọn oniroyin ori ẹrọ ayelujara ti wọn n pe ni Shara Reporters sọ pe ara baba naa ko ya. O ni nitori ailera rẹ lo fi gba ilu oyinbo lọ fun itọju, ki i ṣe nitori ipade kankan gẹgẹ bi awọn kan ṣe n gbe e kiri. Eyi si wa lara idi ti wọn fi sun ipolongo ẹgbẹ naa to yẹ ko bẹrẹ ni Ọjọruu, Wẹsidee, si ọjọ mi-in, ọjọọre.
Ẹgbẹ ti wọn n pe ni National Peace Committee, iyẹn ẹgbẹ to n pe fun alaafia laarin awọn oludibo, eyi ti olori orileede wa tẹlẹ, Ọgagun-fẹyinti Abdulsalami Abubakar ati Biṣọọbu Matthew Kukah n dari ni wọn ṣeto ipade naa.