Jọkẹ Amọri
Ninu ibo ijọba ibilẹ mejidinlogun ti wọn ti ka nipinlẹ Sokoto, oludije sipo aarẹ lorukọ ẹgbẹ APC, Aṣiwaju Bọla Tinubu, lo n lewaju nibẹ.
Esi ibo ti olusakoso eto idibo ipinlẹ naa, Ọjọgbọn Kabiru Bala, ti ka, niṣe ni oludije ẹgbẹ APC ati PDP gbẹnu le ara wọn, ti Labour si wa ni jinna jinna si wọn.
Ibo to le ni igba ati mọkanlelogun o le diẹ (221, 726), ni Tinubu ti ni kaakiri awọn ijọba ibilẹ mejidinlogun ti wọn ti ka bayii.
Ni ti oludije sipo aarẹ lorukọ ẹgbẹ PDP, Atiku Abubakar, oun lo wa nipo keji, to sun mọ Tinubu gbagbaagba pẹlu ibo igba o le mejila ati diẹ (212, 351).
Oludije ẹgbẹ oṣelu Labour, Peter Obi, lo wa lẹyin patapata, ibo ẹgbẹrun mẹfa o le diẹ ni ẹgbẹta (6, 645) loun ni.
Lọwọlọwọ ba a ṣe n sọ yii, wọn ko ti i ka ibo naa tan, o ṣi ku ibo ijọba ibilẹ marun-un ti wọn ko ti i ka. Alakooso eto idibo naa lawọn n lọ fun isinmi, o si di aago mẹsan-an alẹ kawọn too pada wa lati maa tẹsiwaju ninu kika io naa.
Eni to ba rọwọ mu ju ninu awọn ijọba ibilẹ marun-un to ku ti wọn ko ti i ka yii ni yoo jẹ olubori ibo ipinlẹ Sokoto. Ṣugbọn pẹlu bi nnkan ṣe wa lọwọ yii, Aṣiwaju Bọla Tinubu ti APC lo n lewaju
Ninu awọn oludije yii