Tinubu, Sanwoolu wọle ni ibudo idibo wọn

Jọkẹ Amọri

Iroyin to tẹ ALAROYE lọwọ fi han pe oludije dupo aarẹ lẹgbẹ oṣelu APC, Aṣiwaju Bọla Ahmed, lo jawe olubori ni ibudo idibo rẹ to wa ni agbegbe Wọọdu C, Yuniiti kẹrindinlaaadọta(46), Alausa, n’Ikẹja.

Lẹyin ti awọn oṣiṣẹ ajọ eleto idibo to wa ni ibudo idibo naa ka ibo wọn, ninu awọn bii ọọdunrun le mẹrinlelogun (324), ti wọn forukọ silẹ lati dibo, awọn mẹtalelogoji (43) pere ni wọn yọju lati dibo nibẹ.

Ninu awọn mẹtalelogoji yii, Tinubu ni ibo mẹtalelọgbọn (33), Obi to wa ni ipo keji ni ibo mẹjọ, nigba ti Atiku Abubakar ti ẹgbẹ oṣelu PDP ni ibo kan ṣoṣo.

Bakan naa ni ẹgbẹ APC wọle ni ibudo idibo Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwoolu, to wa ni Yuniiti 006, Wọọdu E3, to wa ni Erekusu Eko.

Ibo mẹrindinlaaadọrun-un (86) ni ẹgbẹ APC ni, nigba ti ẹgbẹ oṣelu Labour to wa ni ipo keji ni ibo marun-un (5), ti ẹgbẹ PDP si ni ibo mẹta (3) pere.

Leave a Reply