Adewale Adeoye
Olori orileede yii, Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu, ti paṣẹ pe ki alaga ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ ati ṣiṣe owo ilu ni mọku-mọku nilẹ wa ‘Economic And Financial Crimes Commission’ (EFCC), Ọgbẹni AbdulRasheed Bawa, kuro nipo rẹ.
Igbeṣe yii waye latari awọn ẹsun iwa ibajẹ kan ti wọn ni Bawa hu lasiko to fi wa nipo alaga ajọ naa.
Wọn ni gẹgẹ bii alaga ajọ pataki bii EFCC, ko yẹ ki wọn ba Bawa nidii awọn iwa ti ko daa ti wọn fi kan an yii.
Wọn ni o ṣe pataki lati da Bawa duro lẹnu iṣe to n ṣe yii, ki wọn le ṣẹwadii rẹ daadaa lori awọn ẹsun ti wọn fi kan an bayii.
Bakan naa ni wọn sọ pe ki Bawa ko gbogbo awọn ẹru ijọba gbogbo to ba wa lọwọ rẹ pata fun ọkan pataki lara awọn ọga agba kan to n ri si igbokegbodo akoso iṣẹ ajọ naa titi digba ti wọn yoo fi yan alaga tuntun mi-in.
Ninu atẹjade kan ti alakooso eto iroyin fun Akọwe ijọba apapọ, Ogbẹni Willie Bassey, fi sita l’Ọjọruu, Wesidee, ọjọ kẹrinla, oṣu Kẹfa, ọdun 2023 yii, ni wọn ti fẹsun iwa ibajẹ kan Bawa pe o lo ipo rẹ gẹgẹ bii alaga ajọ EFCC lati fi hu iwa ibajẹ, eyi ti wọn sọ pe ki i ṣohun to daa rara.