Tinubu ti tun tẹkọ leti lọ siluu oyinbo, eyi lohun to n lọọ ṣe

Monisọla Saka

Aarẹ tuntun ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan lorilẹ-ede Naijiria, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, ti tun gbera paa bayii pada si ilẹ Europe, lọsan-an Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹwaa, oṣu Karun-un, ọdun yii.

Tinubu ti ko ti i ju bii ọsẹ meji to de pada silẹ Naijiria, lẹyin abẹwo ti wọn lo ṣe sawọn orilẹ-ede mẹta kan, London, Paris ati Saudi Arabia, ni Tunde Rahman, ti i ṣe agbẹnusọ ẹ tun sọ ninu atẹjade kan to fi sita pe irinajo naa ṣe pataki, nitori ọrọ iṣẹ ni aarẹ tuntun ọhun pẹlu awọn abẹṣinkawọ rẹ kan n tori gbọna ilẹ okeere lọ. Bẹẹ ni wọn ní eto ti wa lori bi yoo ṣe ṣepade pọ pẹlu awọn olokoowo lagbaaye, atawọn eekan mi-in lati le ṣiṣẹ lori ayẹyẹ igbagbarasilẹ ati eto iburawọle fun Tinubu.

Ninu atẹjade yii, Rahman ko sọ orilẹ-ede ti Tinubu n lọ ni pato nilẹ Yuroopu, ṣugbọn o ni laipẹ yii ni yoo dari de lati le waa maa palẹmọ fun eto iburawọle rẹ ti yoo waye lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun yii, gẹgẹ bii aarẹ ilẹ Naijiria kẹrindinlogun.

Ninu atẹjade naa lo ti ni, “Aarẹ tuntun ti rinajo to jẹ mọ ọrọ iṣẹ lọ silẹ Yuroopu, lọsan-an Ọjọruu, Wẹsidee. Nitori iṣẹ ni Aṣiwaju ṣe gba ilu oyinbo lọ. Yoo lo anfaani yii lati pari iṣẹ lori eto iburawọle rẹ, ati awọn ọna iṣejọba rẹ laarin oun atawọn to sunmọ ọn pẹkipẹki, eyi ti yóò mú kí ohun gbogbo lọ bo ṣe yẹ, lai si wahala tabi iruju kankan.

“Lasiko to ba wa lọhun-un, aarẹ tuntun yoo ba awọn olokoowo nla atawọn eekan mi-in ṣepade lori bi wọn ṣe le kọ ileeṣẹ nla ti yoo ṣanfaani fun orilẹ-ede yii, pẹlu bi ijọba rẹ ṣe ti wa ni igbaradi lati faaye gba okoowo lọlọkan-o-jọkan pẹlu aba ati ofin ti wọn yoo la kalẹ.
Lọwọlọwọ bayii, eto ti wa nilẹ lori bi yoo ṣe jokoo Ipade pẹlu awọn onileeṣẹ nla nla nilẹ Yuroopu, to fi mọ awọn ti wọn n pese nnkan, ileeṣẹ eto ọgbin, atawọn ileeṣẹ to jẹ mọ ẹrọ ayelujara.
Igbagbọ Aṣiwaju Tinubu ni lati jere ọkan wọn pe Naijiria ti ṣetan lati ba wọn dowo pọ labẹ ijọba oun, leyii ti yoo mu ki awọn mejeeji jọ jẹ anfaani lori ipese iṣẹ ati eto iṣẹ ọwọ kikọ fawọn araalu”.

O tẹsiwaju pe agbedide eto ọrọ aje ilẹ yii jẹ ọkan pataki lara erongba Tinubu, gẹgẹ bo ṣe han ninu akọmọna ipolongo ibo rẹ ti wọn pe ni, ‘Isọdọtun Ireti’. O ni ipade yii si tun wa lara akitiyan rẹ lati bukun iyi ati ẹyẹ ilẹ Naijiria, lori eto ọrọ aje agbaye, ti yoo si tibẹ ṣeto iṣẹ lọpọ yanturu fawọn ogunlọgọ ọdọ orilẹ-ede yii.”
Ko too gbera kuro nile, Aṣiwaju ṣepade pẹlu ẹni ti yoo di ipo olori ile-igbimọ aṣoju-ṣofin mu, iyẹn Ọnarebu Tajudeen Abbas, ati igbakeji rẹ, Ọnarebu Benjamin Kalu, eyi ti ẹgbẹ oṣelu wọn, All Progressives Congress (APC), buwọ lu, tawọn igbimọ to n ṣiṣẹ papọ ninu ẹgbẹ naa, Joint Task Team, si fa kalẹ niwaju ẹ”.

Ọjọ perete ni wọn ni yoo lo lọhun-un, yoo si pada laipẹ fun ipalẹmọ eto iburawọle rẹ ti yóò waye lọjọ kẹrindinlogun, oṣu Karun-un yii.

Leave a Reply