Faith Adebọla
Yoruba bọ, wọn ni ‘Ta a ba ta a, niṣe la a tọ ọ, ta o ba tọ ọ, o le dẹran onidin’. Owe yii lo ṣe rẹgi pẹu bi awọn ondije funpo aarẹ ninu eto idibo to n bọ yii ṣe n lọ kaakiri lati ri i pe ifa fọ rere fawọn, paapaa lasiko idibo abẹle awọn ẹgbẹ oṣelu wọn. Lọtẹ yii, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, gomina ipinlẹ Eko tẹlẹ ti tun ṣabẹwo pataki kan si Aarẹ ilẹ wa, Muhammadu Buhari, wọn si tilẹkun mọri ṣepade fun bii ọgbọn iṣẹju nirọlẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹta, oṣu Karun-un yii, ni ọfiisi Aarẹ to wa nile ijọba ti wọn n pe ni Aso Rock, lo ti gba Tinubu lalejo.
Lẹyin ti wọn ti fi igunpa ki ara wọn, awọn mejeeji jokoo lati fikun lukun, wọn si le awọn oniroyin atawọn amugbalẹgbẹẹ Tinubu to tẹle baba agba naa jade.
Nigba tipade wọn pari, tawọn oniroyin fọrọ wa Tinubu lẹnu wo bi ijiroro wọn ṣe lọ si, Adari apapọ fun ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC) ọhun sọ pe oun gboriyin fun Aarẹ Buhari bo ṣe tẹle ilana aparo kan o ga ju ọkan lọ laarin awọn ondije fun ipo oṣelu, paapaa fun ipo aarẹ, ati bi Buhari ṣe n fọgbọn bojuto ọrọ eto aabo to mẹhẹ yii. O ni ireti ṣi wa fun Naijiria pe adun ni yoo gbẹyin ewuro orileede naa laipẹ.
Wọn tun bi Tinubi leere ero rẹ lori bi awọn oludije fun ipo aarẹ ṣe n pọ si i ninu ẹgbẹ oṣelu APC ati PDP (Peoples Democratic Party) ati lawọn ẹgbẹ oṣelu mi-in, Baba ẹni aadọrin ọdun naa si fesi pe inu oun dun si i, o ni eyi fihan pe awọn eeyan ko kaaarẹ ọkan lori ọrọ Naijiria, bẹẹ ni wọn o sọreti nu, eyi ni kaluku fi n gbiyanju lati bọ sipo akoso, lati ṣiṣẹ sin orileede naa.
“Gbogbo igbokegbodo yii, ọrọ lati ṣiṣẹ sin ilu lo da le. Ẹni to maa ṣiṣẹ sin ilu gbọdọ ni ero to daa, ko mọ ọna ti yoo tọ, ko si rọ mọ ọna naa lai yẹsẹ. Gbogbo ilakaka rẹ gbọdọ jẹ lati mu igbe aye awọn araalu sunwọn si i, ki idagbasoke ati igbe aye irọrun le wa fun wọn ati fun orileede lapapọ.”
Bi Tinubu ṣe sọrọ yii tan lo ta koro sinu ọkọ ayọkẹlẹ rẹ, o si juwọ sawọn ololufẹ rẹ ti wọn n ṣapẹ si i.
Tẹ o ba gbagbe, Tinubu wa lara awọn to n dije fun ipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC lasiko yii. Baba naa ti gba fọọmu idije ọlọgọrun-un miliọnu Naira lọsẹ to kọja. Titi dasiko yii lo ṣi n fikun lukun lori bi erongba rẹ yoo ṣe kẹsẹ jari, ti yoo si jawe olubori ninu eto idibo abẹlẹ APC lati fa ọmọ oye kalẹ, eyi ti wọn yoo ṣe nipari oṣu yii.