Tinubu yan agbẹjọro aadọta lati koju awọn alatako to gbe e lọ sile-ẹjọ

Orẹoluwa Adedeji

Awọn agbẹjọro bii aadọta ni aarẹ ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan nilẹ wa lati inu ẹgbẹ oṣelu APC, Bọla Ahmed Tinubu, ko jọ bayii lati gba ẹjọ rẹ ro niwaju ajọ to n gbọ awọn ẹsun to ba su yọ lasiko eto idibo ti wọn n pe ni Tiribuna. Alaga ẹgbẹ awọn agbẹjọro nilẹ wa tẹlẹ, Wọle Ọlanipẹkun, ni yoo dari awọn agbẹjọro ọhun, ninu eyi ti adajọ agba ilẹ wa tẹlẹ atawọn agbẹjọro nla nla mi-in wa.

Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ keje, oṣu yii, ni ireti wa pe awọn agbẹjọro naa yoo ṣepade lati le mọ bi wọn yoo ṣe gbe ọrọ ẹjọ naa gba, ati awọn imurasilẹ to yẹ lati mu.

Bakan naa ni ẹgbẹ oṣelu APC funra wọn, iyẹn ẹgbẹ to fa aarẹ tuntun naa kalẹ  ti pe awọn agbẹjọro to lookọ nilẹ wa bii mẹtala ti wọn yoo duro fun awọn ati oludije wọn nile-ẹjọ. Lateef Fagbemi ni yoo ṣaaju awon agbẹjọro naa ni kootu gẹgẹ bi Oludamọrran ẹgbẹ APC lori eto ofin, Ahmad El-Mazuq ṣe ṣalaye niluu Abuja. O ni awọn agbẹjọro ti wọn mọ tifun-tẹdọ ofin, ti wọn si ni iriri nipa ẹjọ to ni i ṣe pẹlu eto idibo lawọn ko jọ lati koju awọn olufisun awọn nile-ẹjọ.

O fi kun un pe awọn yan Fagbemi lati dari wọn nitori pe o ni iriri to pọ, o si ti kopa ninu ọrọ ẹjọ awọn oludibo daadaa.

Tẹ o ba gbagbe, Tinubu ni ajọ eleto idibo ilẹ wa kede pe o jawe olubori pẹlu ibo to le ni miliọnu mẹjọ, to si na awọn alatako rẹ meji to lewaju ju lọ, Atiku Abubakar ati Peter Obi.

Latigba ti ajọ eleto idibo ti kede rẹ gẹge bii ẹni to bori ibo aarẹ ni awọn ti wọn jọ dupo naa ti n fapa janu, wọn ni eru wa ninu ibo naa, ati pe awọn lawọn wọle, ki i ṣe Tinubu. Bi Peter Obi ṣe n sọ pe oun loun wọle ni Atiku naa n sọ bẹẹ. Eyi lo mu ki awọn mejeeji gba ile-ẹjọ lọ.

Igbimọ to n ri si ẹsun to ba su yọ lasiko idibo ni ireti wa pe yoo sọ ibi ti igi ẹjọ naa yoo wo si.

O ni oun gbagbọ pe awọn agbẹjọro ti awọn ko jọ yii to gbangba a sun lọyẹ lati bori ẹjọ naa.

Leave a Reply