Adewale Adeoye
Olori orileede yii, Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu, ti yan Olori ileegbimọ aṣoju-ṣofin ilẹ wa, Ọnarebu Femi Gbajabiamila sipo olori awọn oṣiṣẹ ‘ Chief Of Staff’ (COS) ninu ijọba rẹ, niluu Abuja. Bakan naa ni wọn tun kede iyansipo igbakeji gomina ipinlẹ Jigawa tẹlẹ, Ọgbẹni Ibrahim Hassan sipo igbakeji olori awọn oṣiṣẹ ilẹ yii. Bakan naa lo yan gomina ipinlẹ Benue tẹlẹ, George Akume gẹgẹ bii akọwe ijọba apapọ.
Nibi ipade pataki kan to waye laarin Aarẹ Tinubu atawọn apapọ gomina ti wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC, niluu Abuja, ni Tinubu ti kede iyansipo ọhun, To si tun tun yan gomina ipinlẹ Benue tẹlẹ, to tun jẹ minisita fun akanṣe iṣẹ ninu ijọba Buhari, George Akume, gẹgẹ bii akọwe ijọba apapọ ‘Secretary to The Goverment’ (SGF) fun ijọba rẹ.
Atẹjade pataki kan, eyi ti Akọwe aarẹ, Ọgbẹni Abiọdun Ọladunjoye, fi sita fawọn oniroyin lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ keji, oṣu Kẹfa, ọdun 2023 yii, ni wọn ti sọ pe Tinubu gbe igbesẹ ọhun nitori pe o ni igbagbọ gidi ninu awọn to yan pe wọn yoo ṣiṣẹ naa doju amin ti ko si ni i kabamọ pe o yan wọn sipo naa naa rara.