Tirela sọ ijanu rẹ nu, lo ba lọọ pa Baba Irobo ati iyawo ẹ mọnu ile l’Ado-Ekiti

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Ọkunrin awakọ ẹni ọdun mejilelaaadọta kan ti gbogbo eeyan mọ si Baba Irobo ati Iyawo rẹ ti padanu ẹmi wọn sinu ijamba ọkọ kan to waye ni kutukutu ọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ yii niluu Ado-Ekiti.

Ijamba ọkọ naa waye ni adugbo Dalima, nigba ti ọkọ tirela kan to ko oogun oyinbo padanu ijanu rẹ ni kete to gbẹnu le kọna kan, to si fori le ile alaja meji kan to wa ni adugbo naa.

Gẹgẹ bi ẹnikan ti ìṣẹlẹ naa ṣoju rẹ ṣe sọ, tirela naa ti nọmba idanimọ rẹ jẹ LAGOS 403 XD lo n bọ lati oju ọna kan to lọ sí papa iṣere Oluyẹmi Kayọde. Adugbo Dalima ni wọn ni oun n lọ ni tirẹ, ṣùgbọ́n ni kete to gbẹnu le gẹrẹgẹrẹ kan lo padanu ijanu rẹ, to si ja wọ inu adugbo naa lọ.

Yatọ si Baba Irobo ati iyawo rẹ to ku ninu ijamba ọkọ yii, ọpọlọ dukia lo bajẹ ninu ile alaja meji yii. Awon mẹrin miiran ti wọn fara ̣pa ni wọn ti ko lọ si ile iwosan ìjọba to wa ni ilu Ado-Ekiti.

Nigba ti ALAROYE de ibi ti ìṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ, ọpọ eeyan ati awọn araadugbo naa ni wọn n gbiyanju lati wọ awọn to wa ni abẹ ọkọ naa. Niṣe ni awọn kan n sunkun, ti ọ̀pọ̀lọpọ̀ si kawọ le orí wọn.

Awọn ọdọ adugbo naa ati awọn ẹṣọ alaabo oju popo to je ti ijọba ipinlẹ Ekiti ni wọn gbiyanju lati fa dẹrẹba naa kuro ki wọn le ri awọn tio ha sinu ọkọ naa ko jade.

Iṣẹlẹ yii ṣẹlẹ ni kete to pe ọsẹ mẹta ti iru iṣẹlẹ bẹẹ ṣẹlẹ loju ọna kan naa, ti eeyan mẹrin si fara pa yanayana.

Nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ lori ìṣẹlẹ naa, aAukoro ọlọpaa nipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Sunday Abutu, sọ pe ni kete ti awọn ọlọpaa ti gbọ nipa ìṣẹlẹ naa ni wọn ti ko awọn ẹṣọ oju popo lọ sibẹ.

O ṣalaye pe wọn ti ko awọn to fara pa nibi iṣẹlẹ naa lọ si ile iwosan fun itọju.

Leave a Reply