Faith Adebọla
Gomina ipinlẹ Kaduna, Mallam Nasir El-Rufai, ti sọ pe keku ile gbọ ko sọ fun toko ni o, loootọ lọjọ toun yoo kuro nipo gomina ti sun mọle, amọ iyẹn o ni koun mọwọ ro lori ọrọ wiwo ile ati lile awọn oṣiṣẹ kan danu lẹnu iṣẹ, o ni titi alẹ ọjọ toun maa kuro nipo loun yoo fi maa ba iṣẹ toun gun le naa lọ.
Lọjọ Abamẹta, Satide, ogunjọ, oṣu Karun-un yii, lo sọrọ naa nibi ayẹyẹ ikojade iwe kan ti wọn fi peri rẹ, ati iṣakoso ọdun mẹjọ rẹ nipo gomina ipinlẹ Kaduna.
Ṣaaju ni ọkan lara awọn alejo pataki ti wọn fiwe pe sibi ayẹyẹ to waye ninu gbọngan nla kan nile ijọba ipinlẹ Kaduna, niluu Kaduna naa, Gomina ipinlẹ Rivers, Amofin Nyesom Wike, ti kọkọ sọrọ iwuri nipa iwa akin loju ogun ti olugbalejo rẹ yii ni, o ni ka sọrọ sibi tọrọ wa, bi wọn ba n wa ẹni ti muṣemuṣe rẹ da muṣemuṣe nidii oṣelu, ti wọn si n sọrọ nipa gomina ti ẹnu rẹ tọrọ, ti ki i si i bẹru lati sọ oju abẹ nikoo nigba gbogbo, o loun gba El-Rufai lọgaa, oun si gboṣuba fun un, tori ki i foya lati sọ ero ọkan rẹ jade nigba gbogbo, lai fi ti ẹni tọrọ naa le ta ba pe.
Nigba to to akoko fun un lati sọrọ nibi ayẹyẹ ọhun, El-Rufai dupẹ fun ọrọ oriyin ati apọnle tawọn eeyan ṣe foun, o ni ninu irinajo iṣejọba oun, latigba toun ti kọkọ ṣe minisita, ati nigba toun di gomina, ko si ipenija to sọ oun lorukọ, to si mu kawọn eeyan kan yan oun lọtaa, bii ipinnu oun lati wo awọn ile tawọn eeyan kọ lọna ti ko ba aṣẹ ijọba mu, ati ọrọ awọn oṣiṣẹ ọba ti wọn ko kunju oṣuwọn, ti wọn gbọna ẹburu wọṣẹ ọba, ti wọn si n lu ijọba ni jibiti, toun gba danu bii ẹni figbalẹ gba idọti kuro lọ.
O waa ni: “Ohunkohun ta a ba ri i pe ko daa, oju-ẹsẹ la maa mu un kuro, ki gomina tuntun to n bọ le fọkan balẹ ṣiṣẹ rẹ, ko si lo akoko rẹ lori nnkan mi-in. Ẹ tete kiyesi i o, titi di wakati to kẹyin ti ma a fi kuro nipo gomina la ṣi maa maa da awọn oṣiṣẹ duro, a o si maa wo ile to ba ta ko ilana, atawọn nnkan mi ti ko ba tọ, to ba ti wa si akiyesi wa,” gẹgẹ bo ṣe wi.
Bakan naa ni aarẹ aṣẹṣẹ dibo yan tuntun, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu gboṣuba fun El-Rufai ninu iṣẹ to ran sibi ikojade iwe naa. O ni atoo-fiṣẹ-ogun-ran ẹda kan ni ọkunrin naa i ṣe.