Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Abilekọ kan, Mariam Sọdaq, ti sọ fun Onidaajọ Yunusa Abdullahi, ti kootu ibilẹ kan to wa lagbegbe Akérébíata, niluu Ilọrin, pe ko tu oun ati ọkọ oun, Abdulmujeeb, ti oun bimọ mẹta fun ka, o ni ọrọ rẹ ti su oun, tori bii oro lawọn ṣe maa n ja lojoojumọ, ko si si ifẹ mọ bayii.
Adajọ beere lọwọ Mariam pe bawo ni ọkunrin to gbe wa si ile-ẹjọ naa ṣe jẹ si i ati ibaṣepọ to wa laarin wọn? Mariam ni ọkọ oun ni. Adajọ tun beere pe iru igbeyawo wo ni wọn ṣe, o si dahun pe awọn so yigi ni, tawọn si bimọ mẹta funra awọn.
Nigba ti adajọ beere idi ti wọn fi fẹẹ tu ka, Mariam ni, ‘o ti su mi patapata, gbogbo igba ni a maa n ja’.
Bakan naa ni Mariam rawọ ẹbẹ si adajọ pe ko paṣẹ fun baba awọn ọmọ oun ko maa fun awọn ọmọ naa lowo ounjẹ ati owo itọju nigba to ba rẹ wọn.
Mariam ni ẹgbẹrun lọna aadọrun-un Naira (90k), ni oun fẹẹ maa gba loṣooṣu gẹgẹ bii owo ounjẹ awọn ọmọ mẹtẹẹta.
Ṣugbọn Abdulmujeeb, olujẹjọ sọ ni tiẹ pe, ‘‘Emi ṣi nifẹẹ rẹ, ṣugbọn to ba sọ pe oun ko fẹ mi mọ, emi naa kọ ọ niyawo. Àwọn ọmọ to fẹẹ ko ṣọdọ lo n ba mi lẹru, paapaa ju lọ abikẹyin wa, nitori pe ko le tọju wọn bi mo ṣe fẹẹ. Emi o si ni ẹgbẹrun lọna aadọrun-un Naira (90,000), to ni oun yoo maa gba loṣooṣu gẹgẹ bii owo ounjẹ awọn ọmọ, ẹgbẹrun lọna ogun Naira (20,000), ni agbara mi ka.
Adajọ Yunusa Abdullahi tu igbeyawo naa ka laarin awọn mejeeji, o ni ki wọn o maa lọ lọtọọtọ