‘‘To ba jẹ pe loootọ ni ẹgbẹ PDP fẹẹ rọwọ mu ninu eto idibo aarẹ, iha Guusu/Guusu lo ti yẹ ki wọn fa aṣoju kalẹ’’

Jọkẹ Amọri

Ko ti i jọ pe ọrọ ẹni ti yoo dupo aarẹ lorukọ ẹgbẹ oṣelu PDP ti fori ti sibi kan pẹlu bi awọn gomina lati iha Guusu/Guusu (South-South) ṣe sọ pe bi ẹgbẹ oṣelu PDP ba fẹẹ rọwọ mu ninu idibo sipo aarẹ lọdun to n bọ, afi ki wọn fa oludije kalẹ lati agbegbe naa.

Ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ni awọn gomina to wa lati agbegbe naa pẹlu awọn alẹnulọrọ kan sọrọ yii nibi ipade kan ti wọn ṣe ni Uyo, nipinlẹ Akwa Ibom. Nibi ipade ọhun ti wọn pe ni ‘‘Agbedide eto fun ilẹ Guusu/Guusu lọdun 2023 ati lọjọ iwaju’’ lawọn gomina, awọn ọmọ ileegbimọ aṣofin agba awọn gomina tẹlẹ lati agbegbe naa atawọn agbaagba kan wa ni wọn ti sọ pe bi awọn eeyan ba fẹẹ ṣe ọrọ naa ni la-a-re, pin-in-re, ti wọn ko si ni i ṣe ojuṣaaju tabi ki wọn fi igba kan bọ ọkan ninu, oludije lati agbegbe naa lo yẹ ki wọn fun ni anfaani lati gba tikẹẹti ẹgbẹ yii fun ipo aarẹ.

Awọn eeyan naa sọ pe o ṣee ṣe ki ẹgbẹ naa padanu anfaani lati rọwọ mu lasiko idibo naa bi wọn ko ba fa oludije sipo aarẹ kalẹ ni agbegbe ti wọn ti rẹsẹ walẹ daadaa yii.

Bakan naa ni Gomina ipinlẹ Rivers, Nyesom Wike, sọ pe ki awọn eeyan naa ri i pe awọn ṣe ẹtọ to tọ, ti ko si ni iyanjẹ ninu fun awọn eeyan agbegbe yii. Gomina yii ni pẹlu bo ṣe jẹ pe ẹgbẹ oṣelu naa lawọn eeyan agbegbe ọhun ti n dibo wọn fun lati ọdun 1999, ko waa gbọdọ di asiko yii ki wọn foju tẹmbẹlu ipa ti awọn eeyan agbegbe naa ti ko ninu aṣẹyọri wọn.

Wike fi kun un pe agbegbe Guusu/Guusu yii ni ọpakutẹlẹ ẹgbẹ oṣelu PDP, bi wọn ba si jẹ bẹẹ loootọ, ko yẹ ki iyanjẹ tabi aika wọn si wa rara. O ni loootọ ni gbogbo awọn n poungbẹ pe ki ẹgbẹ oṣelu PDP pada waa gbajọba lọdun 2023, ṣugbọn eleyii ko le ṣee ṣe ti ko ba si ifọwọsowọpọ ati iṣọkan laarin awọn.

Ṣugbọn Alukoro apapọ ẹgbẹ naa, Debọ Ologunagba, ti sọ pe pẹlu ipinnu awọn eeyan Guusu/Guusu yii, awọn ko ni i da ẹnikẹni lati apa Oke-Ọya to ba ti gba fọọmu tabi to ti fi ifẹ han lati dupo naa lọwọ kọ rara.

Tẹ o ba gbagbe, ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, ni Dokita Bukọla Saraki, Aminu Tambuwal ti i ṣe gomina ipinlẹ Sokoto ati Sẹnetọ Bala Muhammed lati ipinlẹ Bauchi ṣepade, ti wọn si fẹnu ko pe awọn ti gba laarin ara awọn lati fa ẹni kan ṣoṣo silẹ ninu awọn oludije lati Oke-Ọya ti yoo dije fun ipo aarẹ.

Ọrọ yii ṣee ṣe ko pada mu awuyewuye lọwọ nitori Alaaji Atiku Abubakar ko si nibi ipade ti wọn ṣe ọhun, wọn ṣẹṣẹ lawọn maa fun un labọ ipade ni. Ko si jọ pe awọn eeyan naa yoo fara mọ ki Atiku gba tikẹẹti naa, yoo fẹrẹ jẹ ọkan ninu awọn mẹta yii ni wọn yoo fẹ lati dije. Pẹlu bi awọn eeyan Guusu/Guusu naa ṣe fi ifẹ han si ipo naa, ọrọ yii yoo rọ ko too to ninu ẹgbẹ ọhun.

 

Leave a Reply