Tọkọ-taya ko tọọgi lọọ lu tiṣa l’Ado-Odo, nitori ọmọ wọn tileewe ni ko gẹrun

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Oju bọrọ ko gbọmọ lọwọ ekurọ lọrọ awọn akẹkọọ ileewe girama nipinlẹ Ogun bayii, bijọba Gomina Dapọ Abiọdun ti n ge wọn lọwọ ni wọn n bọ oruka.

Niṣe ni awọn obi kan tun tẹle ọmọ wọn lọ sileewe l’Ado-Odo pẹlu tọọgi, ni wọn ba lu tiṣa mẹta ni lilu gidi, wọn tun ba mọto olukọ kan jẹ.

Ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu kin-in-ni yii, ni ikọlu kọkọ waye nileewe Toyon High School, l’Ado-Odo Ọta. Akẹkọọ ọkunrin kan torukọ ẹ n jẹ Joshua Joseph, to wa nipele aṣekagba nileewe naa ni wọn ni o gẹ irun buruku sori, o si gbe e wa sileewe bẹẹ.

Irun naa ni  tiṣa kan torukọ ẹ n jẹ Kabir Azeez ni ko lọọ gẹ, ko si pada wa sileewe to ba gẹ ẹ tan. Ṣugbọn kaka ki Joseph lọọ gẹrun ẹ, niṣe lo lọọ rojọ ibẹri fawọn obi rẹ nile, nigba ti yoo si pada wa sileewe, oun, iya ati baba rẹ pẹlu obinrin kan atawọn ọkunrin meji ni wọn jọ wa, wọn waa ba awọn alaṣẹ ja, wọn ni aṣẹ wo ni wọn ni lati le ọmọ awọn jade nileewe.

Igbakeji ọga agba nileewe naa, Abilekọ Mariam Onilogbo, ṣalaye pe boun ṣe ni bi wọn ko ba le tẹle aṣẹ ileewe, ki wọn jade kuro lọgba awọn niyẹn.

O ni bi wọn ṣe jade loun bẹrẹ si i gbọ ariwo ninu ọgba ileewe, ti wọn ti bẹrẹ si i lu awọn tiṣa, ti wọn tun fọ gilaasi iwaju mọto tiṣa kan.

Awọn tiṣa ti wọn lu naa ni Abel Thomas, Kabir Azeez ati Adegun Adekunle, ṣugbọn  eyi ti wọn ṣe leṣe ju ti wọn si fọ ẹnu ẹ ni Kabir Azeez. Orukọ tiṣa ti wọn fọ gilaasi mọto rẹ ni Jọlayẹmi Jeromu.

Nigba ti rogbodiyan naa n lọ lọwọ lawọn alaṣẹ ileewe ranṣe pe awọn ọlọpaa ẹkun Ado Odo, ti DPO Arowojẹun Micheal fi ko awọn ikọ rẹ lọ sibẹ ti wọn si kapa ẹ. Bẹẹ ni wọn mu Baba ati Iya Joshua to waa ja nileewe, orukọ wọn ni Oyedele Nutai Joseph ati Elizabeth Joseph.

Ọsẹ to kọja yii lawọn akẹkọọ ṣẹṣẹ wọle saa keji nipinlẹ Ogun, niṣe si ni ijọba kan an nipa fawọn obi lati kọwọ bọwe adehun pe awọn ọmọ wọn o ni i daamu tiṣa, wọn ko ni i huwa ọmọ buruku nileewe.

Iwe ti wọn kọwọ bọ naa ni fọto akẹkọọ ati ti obi ninu, Baba Joshua yii naa kọwọ bọwe ọhun pẹlu, fọto rẹ ati tọmọ rẹ to da wahala silẹ yii si wa nibẹ. Ṣugbọn ọsẹ kan lẹyin ti wọn wọle lọmọ wọn rufin yii, ti awọn obi rẹ naa si gbe lẹyin rẹ.

Ẹ oo ranti pe awọn ọmọleewe Girama kan dan mẹwaa wo lọdun to kọja, to jẹ bi wọn ṣe n lu tiṣa ni wọn tun fọ DPO kan lori. Obi awọn mi-in si lọwọ ninu rogbodiyan ọhun, wahala lagbara kijọba too gbe awọn ilana ati kapa ẹ jade.

Awọn ọlọpaa ti ti awọn obi mejeeji tọwọ ba yii mọle, CP Lanre Bankọle si ti paṣẹ pe ki wọn ko wọn lọ si kootu laipẹ.

Leave a Reply