Tọkọ-taya ri ọmọ ọdun kan aabọ mọlẹ laaye

Njẹ ẹ gbọ pe tọkọ-taya kan torukọ wọn n jẹ Paul Adoba ati Maame Ataa, ri ọmọ wọn ọkunrin tọjọ ori ẹ ko ju ọdun kan aabọ lọ mọlẹ laaye lọsẹ to kọja yii? Lorilẹ-ede Ghana ni.

Pẹlu iranlọwọ Pasitọ obinrin kan, Ama Nkansah, ni wọn ri ọmọ ọhun mọlẹ leti odo tawọn eeyan agbegbe Brakwa Awoyom, laaarin gbungbun orilẹ-ede Ghana n mu.

Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, awọn lọkọ-laya yii maa n fi gbogbo igba rojọ pe ọmọ ọkunrin awọn naa ko gbadun, wọn ni ilera rẹ ko pe, o si n fi aarẹ naa gbọn awọn lowo danu pẹlu itọju. Wọn ni ẹlẹmi-in okunkun lọmọde naa, wọn ni ọmọ omi ni.

Nitori ẹ ni wọn ṣe lọ si ṣọọṣi Paistọ Ama, Christ Faith International, ni ṣọọṣi ọhun n jẹ, iya to ni in yii si jẹ ẹni ọdun mẹrinlelọgọta (64).

Lẹyin ijiroro lori ọmọ naa, awọn mẹtẹẹta panu pọ lati ri ọmọkunrin naa mọlẹ, wọn si mu Tusidee, ọjọ kin-in-ni, oṣu kẹfa, gẹgẹ bii ọjọ ti wọn yoo ri i mọlẹ, ti yoo maa ba tirẹ lọ sọrun aṣante.

Oru la a ṣeka naa ni wọn fi ṣe, oruganjọ ni wọn ri i mọlẹ, o kan jẹ pe awodi oke wọn ko mọ pe ara ilẹ n wo oun ni.

Ọkunrin kan n gbọ wọn nigba ti wọn n sọrọ laarin oru, nibi ti wọn ti fẹẹ ri ọmọ naa mọlẹ, o dide, o si n yọju loju ferese rẹ, bẹẹ lo ri gbogbo itu ti Paul ati iyawo ẹ, Maame pa pẹlu pasitọ wọn.

O loun sare lọ sibẹ leyin ti wọn sin ọmọ naa tan, oun si ri i pe ilẹpa ti wa nibi ti wọn duro naa, wọn ti sin ọmọ naa sinu saaree laaye.

Ko fi mọ bẹẹ, o loun tun lọọ beere lọwọ awọn obi ẹ nigba tilẹ mọ, niṣe ni wọn sọ pe loootọ, awọn sin ọmọ awọn loru seti odo, nitori awọn gbagbọ pe odo lo fawọn lọmọ ọhun, ko si buru bawọn ba da a pada fodo, ko ṣaa ti kuro laye awọn ni.

Ọrọ di ti ọlọpaa, wọn mu tọkọ-taya yii, ṣugbọn pasitọ wọn sa lọ. Wọn pada ri oun naa mu nigba to fẹẹ ra ounjẹ jẹ  lagbegbe Gomoa Ajumako, ni Ghana.

Ẹsun ipaniyan ni ile-ẹjọ yoo fi kan wọn, iku si ni idajọ rẹ bi wọn ba jẹbi.

Leave a Reply