Faith Adebọla, Eko
Latari biriiji ẹlẹẹkẹrin, Fourth Mainland Bridge, tijọba Eko ati ijọba apapọ fẹẹ pawọ-pọ ṣe, ọgọọrọ lanlọọdu ni yoo di alainilelori, nitori bii ẹgbẹrin ile o din marun-un (795) nijọba lawọn maa wo danu ki iṣẹ naa too ṣee ṣe.
Nibi ijiroro akanṣe kan pẹlu awọn aṣoju ijọba ipinlẹ Eko lẹka eto ayika, eyi to waye lọjọ Ẹti, Furaidee, n’Ikẹja, ni Minisita fun ọrọ ayika, Ọgbẹni Mahmoud Abubakar, ti sọrọ ọhun, o ni ọpọ isapa nijọba mejeeji ti ṣe lati wo ọgbọn ti wọn le da si i ki iye ile ti wọn maa fẹyin ẹ balẹ ma pọ to bẹẹ, ṣugbọn ko si nnkan ti wọn le ṣe si i mọ bayii.
O ni latori nnkan bii ẹgbẹrun mẹsan-an ile atawọn dukia mi-in ti wọn kọkọ lo maa lọ si i lawọn ti fọgbọn dinku, to fi dori ẹgbẹrin yii.
Abubakar ni ko le ma ri bẹẹ, tori kilomita mẹtadinlogoji ni gigun afara naa maa jẹ to ba pari, oun lo maa gun ju lọ ninu awọn afara to gba ori ọsa kọja si Erekuṣu Eko, ati pe biriiji naa maa gba ọna Abraham Adesanya kọja si Ẹsiteeti Sparklite, ko too gori ọsa, gbogbo agbegbe wọnyi si ni ile atawọn dukia kun fọfọ.
O ni lati bii ọdun mẹrin nijọba ti n jẹ ẹ lẹnu lati ṣe afara kẹrin yii, ṣugbọn iṣẹ maa bẹrẹ lori ẹ lọdun 2021, tori iwulo biriiji naa kuro ni kereemi. O ni biriiji yii, yatọ si bo ṣe maa mu ki irinajo lati Eko si Erekuṣu Eko ya kankan, o tun maa so ipinlẹ Eko pọ mọ ipinlẹ Ogun taarata ni.
Ọgbẹni James Kọlawọle, to gbẹnu minisita naa sọrọ sọ pe eto gidi ti n lọ lọwọ lati ri i pe wọn ṣe owo fawọn ti wọn maa padanu ile ati dukia wọn, ki wọn si pese iranwọ to yẹ.
Bakan naa ni Ọgbẹni Abayọmi Ọmọlọla Amos to jẹ eleto ilu (town planner) lẹka eto ayika sọ pe awọn ko ti i jawọ ninu wiwa gbogbo ọna ti iye ile ti wọn maa wo yoo fi tubọ dinku.