Wọn dana sun ole meji niluu Ileefẹ

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Awọn ole meji ti wọn sọ pe wọn ji ọkada lawọn araalu binu dana sun niluu Ileefẹ, lọsan-an ọjọ Ẹti, Furaidee.

Gẹgẹ bi awọn tiṣẹlẹ naa ṣoju wọn ṣe sọ fun akọroyin wa, awọn ọkunrin mejeeji ti gba ọkada kan lagbegbe Lagere, ṣugbọn kia lawọn ọlọkada ti wọn wa nibẹ sare tẹle wọn, ti wọn si ri wọn mu.

Lẹyin ti wọn lu wọn bii kiku bii yiye ni wọn dana sun wọn sẹgbẹẹ titi nibẹ.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun, Yẹmisi Ọpalọla, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o ni ki awọn ọlọpaa too debẹ ni wọn ti dana sun wọn.

 

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Nitori to ni oun yoo fopin si eto aabo ni Borno ati Yobe, PDP Ekiti sọrọ si Fayẹmi

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti Ẹgbẹ PDPipinlẹ Ekiti ti yẹgẹ ẹnu si gomina ipinlẹ Ekiti, Dokita Kayọde …

Leave a Reply

//zikroarg.com/4/4998019
%d bloggers like this: