Tori bo ṣe tu aṣiri awọn eeyan nla to wa ninu ijọba Buhari to n ṣatilẹyin fun Boko Haram, awọn ọtẹlẹmuyẹ n wa Ajagun-fẹyinti Ọlawunmi

Faith Adebọla, Eko

 Awọn ọtẹlẹmuyẹ ileeṣẹ ologun ilẹ wa, Defence Intelligence Agency ti kede pe ki Ajagun-fẹyinti Kunle Ọlawunmi yọju sawọn lai sọsẹ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, to n bọ yii, ko si gbọdọ gbagbe iwe irinna kari-aye rẹ sile o, wọn loun ati iwe naa ni ki wọn jọ de ọfiisi awọn l’Abuja, awọn fẹẹ beere ọrọ lọwọ rẹ latari awọn ọrọ aṣiri kan ti wọn lọkunrin naa sọ faye gbọ laarin ọsẹ yii.

Lasiko ifọrọwanilẹnuwo kan ti wọn ṣe fun Navy Commodore Kunle Ọlawunmi (Retired), to ti figba kan jẹ ọga pata fawọn ọmọ-ogun ori omi ilẹ wa, nileeṣẹ tẹlifiṣan Channels ni wọn lọkunrin naa ti fẹnu kọ, wọn lo tu aṣiri pe alabosi nijọba Buhari, abosi nla nijọba naa n ṣe, tori ọpọ iṣẹ iwadii ti wọn ti ṣe nipa eto aabo to mẹhẹ paapaa lapa ilẹ Hausa lo fihan pe awọn ọtọọkulu ati oloṣelu nla nla  kan lo mori mu, ti wọn n kona mọ iwakiwa awọn afẹmiṣofo naa labẹnu.

Ọkunrin naa tun sọ pe ko si eyi ti Aarẹ Muhammadu Buhari ko mọ ninu wọn, gbogbo  wọn niṣẹ iwadii awọn ọtẹlẹmuyẹ ti gbe jade, ti wọn si ti forukọ wọn ṣọwọ si Aarẹ, ṣugbọn ọwọ yọbọkẹ nijọba fi mu ọrọ ọhun, niṣe lo gboju ṣẹgbẹẹ kan lori ọrọ wọn, eyi lo si fa a to jẹ kaka ki ewe agbọn dẹ, niṣe lọrọ awọn eeṣin o kọku naa n le koko si i.

Aṣiri mi-in ti wọn tun tori ẹ fẹẹ mu Kunle si ni bi wọn ṣe lo sọ ninu ifọrọwanilẹnuwo naa pe: “Ejo lọwọ ninu ni o, bi wọn ṣe lọọ sakọlu si ileewe ẹkọṣẹ oloogun (Nigerian Defence Academy), ti wọn si mu un jẹ yii, o ni bo ṣe jẹ ni, tori iru nnkan bayii ko le ṣadeede waye.

Ṣugbọn mo ranti nigba kan ti mo n ṣiṣẹ iwadii ati ọtẹlẹmuyẹ kan, mo ranti pe wọn ki i pa ilẹkun geeti awọn ileeṣẹ ologun de lọjọ Ẹti, Furaidee, kawọn ologun ti wọn fẹẹ lọọ kirun Jumat, ero n lọ, wọn n bọ ni, lọpọ ọjọ Furaidee, o si ti wa bẹẹ tipẹ. Ibi tawọn eeyankeeyan naa gba wọle si wọn lara niyẹn, ibẹ ni wọn ti mọ aṣiri wa ti wọn fi raaye ṣe iru ọṣẹ nla bẹẹ.’’

Wọn ni Kunle tun sọ pe: “Mo sọ fun Ọgagun Oloniṣakin nigba kan pe bi ina ko ba l’awo, ko le jo goke odo, pe iṣoro awọn afẹmiṣofo yii ko jọra pẹlu tawọn ajijangbara Naija-Delta. Mo ni koko ọrọ to wa nidii iwa buruku awọn Boko Haram ni ti awọn to n ṣe onigbọwọ wọn, lara wọn si wa ninu awọn to n ba Buhari ṣejọba yii. Awọn ni wọn n pe ole waa ja, ti wọn si n pe oloko lati waa mu un. Laiṣe pe Buhari ba ṣetan lati ṣiṣẹ lori awọn agbẹyin-bẹbọjẹ wọnyi, ina iwa ibi yii ko le ku. Ṣugbọn ko jọ pe Buhari fẹẹ ṣiṣẹ lori wọn, tori o mọ wọn, awọn eeyan nla nla ni wọn.”

Olobo kan to ta awọn oniroyin fihan pe ọrọ yii ti da ọpọ họu-họu silẹ nileeṣẹ Aarẹ ati ileeṣẹ ologun ilẹ wa, wọn si ti pinnu lati fi pampẹ ofin gbe Kunle, ki wọn si gbẹsẹ le pasipọọtu rẹ pẹlu.

Laipẹ yii ni wọn mu awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ Channels tẹlifiṣan to kopa ninu ifọrọwanilẹnuwo naa lọọ sileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ, ki wọn too fi wọn silẹ lọjọ keji.

Leave a Reply