Tori gbese owo gbọmu-le-lanta to jẹ, Iya Dada dana sun’ra ẹ l’Abẹokuta

Gbenga Amos, Abẹokuta

Obinrin kan ti wọn n pe ni Mama Dada, ti ro ile aye ẹ pin lori ẹyawo banki alabọọde LAPO ti wọn n fi ẹfẹ pe ni ‘gbọmu-le-lanta’ ti wọn lo gba, ẹgbẹrun lọna aadọrin Naira, sẹbinti taosan, (N70,000) ni wọn pe owo ọhun, eyi ti ko rọna da pada, lo ba ro o pe iku ya ju ẹsin lọ, lo ba ti ara rẹ mọ inu yara kan to rẹnti ninu ile to n gbe, o bu epo bẹntiroolu wọn gbogbo ile naa, o si ṣana si i, bẹẹ lo ṣe dana sun ara ẹ mọle, to fi jona gburugburu.

Iṣẹlẹ yii la gbọ po waye laduugbo Oke-Keesi, ni Itoko, niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun, lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kejidinlogun, oṣu Keji yii.

Awọn aladuugbo tiṣẹlẹ naa ṣoju wọn sọ pe nigba ti wọn yoo fi ri ina naa pa, obinrin yii to jona mọle, ko sẹni to le da a mọ mọ, latari bi ina naa ṣe jo oun ati awọn dukia to wa ninu ile naa.

Wọn ni lọjọ iṣẹlẹ yii, funra ẹ lo ke si ọkan ninu awọn ọmọ ẹ ti wọn jọ n gbe, o ni kọmọ naa lọọ ba oun ra epo bẹntiroolu wa, ko si sẹni to fura pe nnkan aburu kan lo fẹẹ fepo naa ṣe.

Lẹyin tọmọ gbepo de, wọn lo dọgbọn tan gbogbo awọn ọmọ naa sita, lo ba tilẹkun yara mọ ara ẹ latẹyin, ko too gbẹmi-in ara ẹ.

Alaamulegbe oloogbe yii kan, Raheed Aina, to ba awọn oniroyin sọrọ sọ pe tori gbese ẹyawo ẹgbẹrun lọna aadọrin Naira ni Iya Dada ṣe pa ara ẹ. Wọn ni owo naa ko to bẹẹ nibẹrẹ, amọ nigba ti gbogbo igbiyanju rẹ lati sanwo naa ko bọ si i, ti ẹlewo, ti wọn n pe ni intirẹẹsi n gori owo naa lọsọọsẹ lowo ba di gọbọi. O ni gbogbo igba lobinrin yii maa n ṣaroye nipa bi ọkan rẹ ko ṣe lelẹ latari gbese naa.

Bakan naa ni Akọwe ẹgbẹ idagbasoke adugbo wọn, CDA, Ọgbẹni Babawale, jẹrii si i pe loootọ ni obinrin naa gba owo LAPO, ti wọn n pe ni gbọmu-le-lanta, ẹgbẹrun lọna aadọrin lo wa lọrun ẹ, tori ko ri owo naa san, ko si mọna to le gbe e gba lo fi gbe igbesẹ iku gbigbona to gbe.

A gbọ pe wọn ti gbe Mama Dada lọ sile igbokuusi to wa lọsibitu Jẹnẹra Ijaye, l’Abẹokuta, wọn si ti ranṣẹ sawọn mọlẹbi ẹ kan.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, SP Abimbọla Oyeyẹmi naa ti fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, ṣugbọn o loun ko ti i le sọ hulẹhulẹ nipa rẹ tori iwadii ṣi n lọ lọwọ.

Leave a Reply