Faith Adebọla, Eko
Pẹlu bi agbẹjọro Ahmed Micheal, baale ile ẹni ọdun mẹtalelọgbọn ti wọn fẹsun ifipabanilopọ kan ṣe rawọ ẹbẹ pe ki wọn ṣiju aanu wo onibaara rẹ to, adajọ gbe idajọ kalẹ lori ẹjọ naa, ifa ko si fọre rara fun un, ẹwọn gbere ni wọn ju ọkunrin naa si, wọn ni ko lọọ lo iyooku aye ẹ ni keremọnje.
Bi wọn ṣe ṣalaye ni kootu akanṣe to n gbọ ẹsun iwa ọdaran abẹle ati ifipabanilopọ naa l’Ọjọbọ, Tọsidee, to kọja yii, ọmọbinrin ẹni ọdun mọkanlelogun kan ti wọn forukọ bo laṣiiri lọdaran naa fipa ṣe ‘kinni’ fun.
Lọdun 2013 ti iṣẹlẹ naa waye, iṣẹ ọkada ni Micheal n ṣe, wọn lọmọbinrin naa n dari rele rẹ lati ṣọọṣi lẹyin isin ọjọ Sannde ni lọjọ ọhun, ni Micheal ba gbe e gẹgẹ bii ero.
Amọ kaka ko gbe e lọ si adirẹsi rẹ, ojiji ni ọlọkada ọdaran yii ya biri, lo ba gbe ọmọ naa lọ sile akọku to wa ninu ẹsiteeti kan, bo ṣe di pe o fipa ba ọmọọlọmọ laṣepọ loju ọlọmọ-o-to-o lọjọ naa niyẹn.
Ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Keje, ọdun 2013, ọhun lọwọ pada tẹ ẹ, ti wọn si foju rẹ bale-ẹjọ, lẹyin iwadii. Bo tilẹ jẹ pe Micheal kọkọ fariga pe oun ko ṣe nnkan to jọ mọ ẹsun ti wọn fi kan oun ri, o ni irọ lọmọbinrin naa n pa mọ’un, ṣugbọn nigba to ya, o jẹwọ niwaju adajọ pe ki wọn ṣaanu oun. Lọọya rẹ, Ọgbẹni Bashir Ramon, ni onibaara oun ko da iru ẹṣẹ yii ri, tori bẹẹ, ki wọn fi eyi fa a leti.
Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, Adajọ Hakeem Oṣodi ni ẹri olupẹjọ ko ruju rara lori ọrọ yii, ṣugbọn olujẹjọ yii gbiyanju lati doju ẹjọ ru, o fẹẹ ṣi ile-ẹjọ lọna.
O ni ọtọ lorukọ to n jẹ, ọtọ lorukọ to sọ fawọn agbofinro, ati pe ẹri tun fihan pe loootọ lo fi tipa laṣepọ pẹlu ọmọbinrin naa, tori apa ibi to ti ge e jẹ lejika wa lara rẹ. Nitori eyi, o lo jẹbi ifipabanilopọ ati ṣiṣe akọlu sọmọlakeji ẹ.
Ẹwọn ọdun mẹta ni wọn sọ ọ si fun ṣiṣe akọlu, ṣugbọn ti ifipabanilopọ, ẹwọn gbere ni wọn da fun un. O ni sẹria to kere ju lọ tile-ẹjọ laṣẹ lati da fẹni to ba jẹbi ẹsun ifipabanilopọ niyẹn, ko si ṣee ṣe lati dajọ to din si iyẹn.