Faith Adebọla
Ajọ eleto idibo apapọ ilẹ wa, Independent National Electoral Commission, ti juwe ile fun ọgọrun-un lara awọn oṣiṣẹ rẹ, wọn lawọn eeeyan naa lọwọ ninu eru ati iwa irufin lasiko eto idibo to kọja.
Kọmiṣanna fun ajọ INEC nipinlẹ Akwa Ibom, Dokita Cyril Omorogbe lo sọrọ yii di mimọ l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹta, ọdun 2023 yii.
Ninu ifọrọwerọ kan to ṣe pẹlu Ajọ Akoroyinjọ ilẹ wa (NAN), niluu Uyo, olu-ilu ipinlẹ naa, lo ti sọ pe awọn oṣiṣẹ ti wọn le danu naa jẹ awọn ti wọn gba lati ṣamojuto eto idibo sipo aarẹ ati tawọn aṣofin apapọ, eyi to waye kọja yii, amọ to jẹ ohun ti wọn ni ki Ẹlẹmọṣọ wọn ṣọ kọ ni wọn ṣọ, ti iwadii si ti fi han pe ọwọ wọn ko mọ lori iṣẹ ti wọn yan fun wọn.
“Niṣe la yọ orukọ wọn danu kuro lara awọn oṣiṣẹ wa, a o si ni i lo wọn lasiko eto idibo sipo gomina ta a fẹẹ ṣe lọjọ Satide yii. Orukọ wọn ti wa lara awọn ti INEC ko tun jẹ ya sakaani wọn mọ fun ohunkohun lọjọ iwaju. Ọpọ ninu wọn ni iwadii ti fidi ẹ mulẹ pe niṣe ni wọn mọ-ọn-ọn gbẹyin bẹbọjẹ lasiko eto idibo to kọja, wọn lọwọ ninu iwa eru ati magomago.
“Yatọ si lile ta a le wọn yii, lẹyin ti eto idibo gbogbogboo ba ti pari, INEC ṣi maa ṣe ipinnu lori wọn, o ṣee ṣe kawọn kan dero ile-ẹjọ tabi ki wọn tiẹ rẹwọn he pẹlu” gẹgẹ bo ṣe wi.
Bakan naa ni kọmiṣanna yii sọ pe awọn aleebu diẹ to waye pẹlu ilo ẹrọ wa lara nnkan tawọn ti ṣiṣẹ le lori, ti ireti si wa pe eto idibo to kan, iyẹn ti gomina ati awọn aṣofin ipinlẹ, yoo lọ bo ṣe yẹ, lai si aroye ta ko INEC ati awọn nnkan eelo wọn.
“Mo le fi da yin loju pe awọn ipenija ta a koju lasiko eto idibo to kọja yii, a o ni i jẹ kiru ẹ waye leyii to n bọ yii,” bo ṣe n kadii ọrọ rẹ.