Faith Adebọla
Bawọn eeyan yoo ṣe maa ki ara wọn ‘api niu wiiki’ ni gbogbo ọjọ Mọnde, iyẹn ikini ọsẹ tuntun, pẹlu ireti pe nnkan yoo ṣenuure fun koowa lọsẹ naa, ni ti ilumọ-ọn-ka onkọrin hipọọpu kan, Habeeb Okikiọla Ọlalọmi, tawọn eeyan mọ si Portable olorin, tabi Zah zuu zeh, ẹjọ lọkunrin naa yoo fi bẹrẹ ọsẹ tuntun tiẹ, tori ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹta, oṣu Kẹrin, ọdun yii, nijọba yoo wọ ọkunrin to fẹran lati maa daṣa “Idaamu adugbo yin ti de o” yii tuuru rele-ẹjọ, ẹsun mẹfa ọtọọtọ ni wọn pese silẹ de e, ti wọn yoo fi ki i kaabọ, ti yoo si bẹrẹ si i kawọ pọnyin rojọ lori awọn ẹsun naa.
Amọ, ohun to kọju sẹnikan, ẹyin lo kọ sẹlomi-in bii ilu gangan, latari bawọn eeyan ṣe bẹrẹ awuyewuye lori bijọba ṣe fẹẹ ba Portable ṣẹjọ, wọn ni ileeṣẹ ọlọpaa n ṣojuṣaaju, wọn ni ohun ti ọga ẹgbẹ awọn onimọto tẹlẹri nipinlẹ Eko, Alaaji Musilu Ayinde Akinsanya, tawọn eeyan mọ si MC Oluọmọ ṣe, ọrọ idunkooko mọ ni to sọ lasiko eto idibo gbogbogboo to kọja yii buru ju ẹsun ti wọn ka si Portable lọrun lọ, wọn nileeṣẹ ọlọpaa n ṣojuṣaaju, wọn fẹsun kan wọn pe niṣe ni wọn daṣọ bo iwa aidaa MC Oluọmọ lori, pe wọn ti ka ọkunrin naa si ‘aṣẹ-ma-lu ẹran ọba’, amọ Portable tọrọ tiẹ ko le ni wọn sare fi pampẹ ọba mu, ti wọn si n ba a ṣẹjọ.
Ẹnikan to porukọ ara ẹ ni Shotayọ Toby lori ikanni abẹyẹfo, iyẹn tuita, lo fọrọ ṣọwọ si Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa apapọ, CSP Olumuyiwa Adejọbi, lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kin-in-ni, oṣu Kẹrin yii, pe “Lori iwa ti Portable hu, ẹ ti sare firoyin lede pe onijangbọn eeyan ni, ṣugbọn nigba ti MC Oluọmọ kede ta ko ẹtọ awọn araalu lati dibo fẹni to wu wọn, ẹ feti palaba ẹ, ẹ gboju sẹgbẹẹ kan bii pe ẹ o gbọ ọrọ to sọ, igba tẹ ẹ si maa fesi, ileeṣẹ ọlọpaa ni apara lasan ni MC Oluọmọ n da, ṣe ẹ ti waa ri i bayii pe gbogbo wa ti di alaapara patapata lorileede yii.”
Bọrọ yii ṣe balẹ sori ikanni Alukoro Adejọbi lo ti ki gege rẹ mọlẹ, o si fesi bayii pe: “O da mi loju pe ẹ o sun nigba ti mo sọrọ lori ẹsun ti wọn fi kan MC Oluọmọ lọjọsi, ṣugbọn ti Portable yii, ẹsun to wa lọrun ẹ ju mẹfa lọ, yatọ si pe o gbegi dina fawọn ọlọpaa lati arẹẹsi ẹ, o tun ṣe ọlọpaa kan leṣe. A maa wọ ọ lọọ sile-ẹjọ pe o lu ọkunrin kan lalubami ni Ọta, ipinlẹ Ogun, ọkunrin to lu ọhun lo kọwe ẹsun nipa rẹ sọwọ si kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, iwe naa la si n ṣiṣẹ le lori.”
O tẹsiwaju pe: “Ọpọ ẹjọ lo wa nilẹ fun Portable lati jẹ, awọn ẹsun oriṣiiriṣii nipa bo ṣe n ṣakọlu sawọn eeyan, to n gbeja ko wọn, to n lu awọn mi-in tabi ko paṣẹ fawọn bọisi ẹ lati lu wọn, gbogbo ẹsun yii la maa tuṣu rẹ desalẹ ikoko, tori awọn eeyan o jẹ ka rimu mi pẹlu bi wọn ṣe n kọwe ẹsun nipa rẹ.
“Tori ẹ, ko si ojuṣaaju labẹ ofin o, ẹ jẹ ko fara han ni kootu na, ẹ jẹ kadajọ tẹti si awọn ẹsun ta a fi kan an. Tori ko si ofin ‘ma fọwọ kan ọmọ mi’ ti wọn n pe ni imuniti fun Portable o.”
Sibẹ, alaye yii ko jọ pe o tẹ awọn eeyan lọrun pẹlu ẹsun agabagebe, ati ilana dida ọkan si, yiyan ọkan nipọsin, ti wọn fi kan ileeṣẹ ọlọpaa ilẹ wa lori Portable olorin to fẹran lati maa daṣa “wahala, wahala, wahala” ninu awo rẹ, ati alaga igbimọ to n mojuto awọn ibudokọ nipinlẹ Eko lọwọlọwọ, Lagos State Parks and Garrages Management Committee, MC Oluọmọ.
Ẹnikan to porukọ tiẹ ni Son of Bevu sọ pe “Adejọbi, ko si bo o ṣe fẹẹ sọ fun mi pe MC Oluọmọ ko ga ju ofin lọ ni Naijiria o, tori pẹlu ọrọ alufanṣa to sọ lasiko idibo, o ṣi n rin, o yan fanda kiri igboro, pẹlu gbogbo bi wọn ṣe ba dukia jẹ, ti wọn si ṣe awọn eeyan leṣe latari ọrọ idunkooko mọ ni rẹ. Itan lẹyinwa ọla ko ni i ṣojuure sawọn ti wọn n fi ọrọ awọn araalu ti wọn n sanwo-ori wọn ṣe oṣelu o.
Ni ti Kush Alabi, ibeere loun beere, o ni: “Ẹ jọọ, ẹ fi han mi ibi tẹ ẹ si gbe igbesẹ lori ọrọ MC Oluọmọ o, ẹ jẹ ka gbọ.”
Bayii lawọn eeyan kọ ọrọ lọkan-o-jọkan.
Tẹ o ba gbagbe, lasiko ti idibo sipo gomina atawọn aṣofin ipinlẹ, eyi to waye lọjọ kejidinlogun, oṣu Keji yii, ku ọjọ diẹ ni fidio kan bẹrẹ si i ja ranyin lori ẹrọ ayelujara, nibi ti MC Oluọmọ ti n ba awọn alatilẹyin ẹgbẹ oṣelu APC sọrọ, nibẹ lo ti sọ fun wọn pe ko pọn dandan fun ẹnikẹni lati dibo fawọn o, amọ ki wọn sọ fẹni ti ko ba fẹẹ dibo fawọn lati ma ṣe jade o, o darukọ Iya Chukuwdi, pe ki wọn ma jade o, ati bẹẹ bẹẹ lọ. Ọrọ yii da ọpọ awuyewuye silẹ, bo tilẹ jẹ pe lẹyin naa ni MC Oluọmọ tun ṣe fidio mi-in, oun atẹni to loun n pe ni Iya Chukwudi, o ni apara lasan loun fi ọrọ ti wọn n gba bii ẹni gba igba ọti naa ṣe o, oun ko miinni ẹ bawọn eeyan ṣe n sọ yẹn.
Ni ti Portable, lati ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu yii, loun ti balẹ sakata awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ni olu-ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun to wa l’Eleleweeran, l’Abẹokuta. Awọn ọlọpaa ni wọn lọọ fi pampẹ ofin gbe e lẹyin ti wọn ti fun un ni gbedeke wakati mejilelaaadọrin pe ko yọju sawọn, tori awọn fẹẹ bi i lawọn ibeere lori ọkan-o-jọkan ẹsun tawọn eeyan fi kan an, ṣugbọn ti ‘Idaamu Adugbo’ ta ku, ti ko yọju.
Ẹ oo ranti pe laarin ọsẹ to lọ naa, ṣaaju gbedeke yii ni Portable fariga m’awọn ọlọpaa ti wọn fẹẹ mu un nile itaja ati ọfiisi rẹ kan nipinlẹ Ogun lọwọ, o ni sẹlibiriti loun, iyẹn gbajumọ oṣere, ko si tọna lati mu oun bii ẹni he igbin bẹẹ, ati pe oun ṣiṣẹ fun APC, wọn o si le maa ko ibọn wọ ọfiisi oun bo ṣe wu wọn, lo ba yari mọ wọn lọwọ.