Tori wọn yinbọn fawọn maaluu to n jẹko lagbegbe wọn, ọlọpaa ju awọn ọdọ mẹta sahaamọ l’Eruwa

Faith Adebọla

 Ahamọ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ lawọn ọdọ mẹta ọmọ bibi ilu Eruwa yii, Ọpẹyẹmi Ajibọdun, ẹni ọgbọn ọdun, Ṣẹgun Dade, ẹni ọdun mọkandinlọgbọn ati Dare Adenle, ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn, wa lasiko yii latari bi wọn ṣe fẹsun kan wọn pe awọn ni wọn yinbọn fawọn maaluu to n jẹko lagbegbe Eruwa lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, Ọgbẹni Adewale Ọṣifẹsọ, sọ pe adugbo Sunbare, niluu Eruwa, nijọba ibilẹ Ila-Oorun Ibarapa niṣẹlẹ naa ti waye, o ni niṣe lawọn araalu kan n gburoo ibọn leralera loru mọju ọjọ Sannde si Mọnde ọhun, nigba tilẹ si mọ tawọn agbofinro lọọ wo ohun to n ṣẹlẹ, wọn ba oku maaluu mẹfa ti wọn yinbọn fun, awọn Fulani darandaran mẹtala lo si fara gbọgbẹ yannayanna.

O nigba tawọn fimu finlẹ lawọn ri i pe awọn afurasi ọdaran mẹta yii wa lara awọn to ṣiṣẹ naa, eyi ni wọn fi mu wọn.

O tun ṣalaye pe lasiko ti wọn lọọ fi pampẹ ofin mu wọn, ibọn ibilẹ meji, awọn ọta ibọn ti wọn ti yin ateyi ti wọn o ti i yin, oogun abẹnu gọngọ, ọbẹ aṣooro, ada kan, ina tawọn ọlọdẹ maa n so mọ’ri, kaadi ATM mẹta ti wọn lo jẹ ti Ajibọdun Ọpẹyẹmi, iṣana eebo kan ati awọn nnkan ija mi-in ni wọn ba lọwọ wọn.

O lawọn afurasi naa jẹwọ pe niṣe lawọn n fibọn le awọn Fulani darandaran naa kuro lagbegbe awọn tori wọn ti kilọ fun wọn tẹlẹ pe ki wọn yee fẹran jẹko ni gbogbo agbegbe ọhun, ṣugbọn lọpọ igba, ọganjọ oru lawọn darandaran naa fi n boju lati ṣiṣẹẹbi wọn.

Ọṣifẹsọ ni iṣẹ iwadii ṣi n tẹsiwaju lori iṣẹlẹ yii.

Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ naa ti gbọ si iṣẹlẹ yii, o si ti fọwọ sọya pe idajọ ododo maa waye lori ẹ tiṣẹ iwadii tawọn n ṣe ba ti pari.

 

 

Leave a Reply