Toromagbe, baba Oriṣabunmi ninu sinima Arelu, ti ku o

Aderounmu Kazeem

Ọgbọnjọ oṣu kọkanla ọdun yii ni wọn sọ pe Oloye Abdul Tawab Ọlaitan Ile-Aje Adeniyi, ẹni tawọn eeyan tun mọ si Toromagbe jade laye.

Ọkan lara awọn oṣere ti wọn gbajumọ daadaa ni ọkunrin yii n ṣe lasiko ti sinima Arelu, ti Ọloogbe Jimoh Aliu, ẹni tawọn eeyan tun mọ si Aworo, gbalẹ daadaa ni gbogbo ilẹ Yoruba atawọn ibomi-in kaakiri.

Mọlebi oloogbe yii, Oloye Tọla Adeniyi, lo kede iku ẹ, oun naa lo sọ pe ọdun mẹtalelọgọta ni oṣere tiata yii lo laye ko too dagbere wi pe o digbooṣe.

Ninu sinima Arelu, ti okiki ẹ kan daadaa ni nnkan bi ọgbọn ọdun sẹyin, Toromagbe yii lo ṣe baba Oriṣabunmi, ẹni ti i ṣe ọkan pataki ninu awọn ojulowo oṣere ninu fiimu ori tẹlifiṣan naa.

Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, yatọ si ipa iwin to ko ninu ere naa, wọn ni oṣere kan to mọ ijo jo daadaa ni, bẹẹ lo tun ni awọn ẹbun mi-in, eyi to fun orukọ tiata tiẹ naa, Tawab Theatre, lanfaani lati rin irin-ajo kaakiri Naijiria atawọn ibi kan nilẹ Afrika.

Leave a Reply