Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Awọn afurasi mẹta kan ni wọn ti n kawọ pọnyin rojọ bayii fẹsun pe wọn gbimọ-pọ pẹlu ọmọkunrin kan, Shehu Usman, lati ji baba rẹ gbe nitori ẹgbẹrun lọna ọọdunrun Naira (#300,000).
Awọn afurasi mẹta naa, Sanni Na-Hamzat, Abdullahi Sayi ati Mohamodu Kabiru, nile-ẹjọ Majistreeti kan niluu Ilọrin, nipinlẹ Kwara, ti ni ki wọn lọọ sọdun tuntun lọgba ẹwọn Oke-Kura, fun ẹsun ọdaran ati igbimọ pọ ji ni gbe, eyi to ta ko ori kẹtadinlọgọrun-un, ati ikarundinlọgọrun-un, iwe ofin ilẹ wa.
Iroyin ta a gbọ lẹnu awọn ọlọpaa ni pe Baba Usman, gba ipe kan lati ọwọ awọn ajeji kan ti ko mọ, ti wọn si n halẹ mọ ọn lori foonu pe ko fi ẹgbẹrun lọna ọọdunrun Naira ṣọwọ kiakia to ba ni ẹmi rẹ i lo. Ṣugbọn to ba kọ lati san owo naa, a jẹ pe o fẹẹ siyan laye ko lọọ gbọbẹ lajule ọrun ni.
Ọlọpaa ni nigba ti iwadii bẹrẹ lawọn too mọ pe foonu ọmọ baba yii ọkunrin to n jẹ Shehu Usman, ni wọn fi n pe. Pẹlu akitiyan awọn agbofinro, wọn mu awọn afurasi mẹtẹẹta tọmọ naa bẹ lọwẹ si baba rẹ, ṣugbọn ọmọ baba yii sa lọ, awọn ọlọpaa ṣi n wa a titi di bi a ṣe n ko iroyin yii jọ.
Agbefọba, Gbenga Ayeni, rọ ile-ẹjọ pe ki wọn ju awọn afurasi naa sahaamọ tori pe ọdaran paraku ni wọn.
Onidaajọ Dasuki, paṣẹ pe ki wọn lọọ ju wọn si ọgba ẹwọn Oke-Kura, o sun igbẹjọ si ọjọ kẹtadinlogun, oṣu kin-in-ni, ọdun 2023.