Victor yii buru o, pẹlu arun ko gboogun to wa lara ẹ lo fi fipa ba ọmọ ọdun mẹrin lo pọ

Adewale Adeoye

Awọn eeyan ilu Umuahia, nipinlẹ Abia, ti sọ pe awọn ko ni i fọwọ yọbọkẹ mu ẹsun iwa ọdaran kan ti wọn fi kan Ọgbẹni Chiemela Victor Ekeke, ẹni ọdun mẹtadinlogoji rara. Ẹsun ti wọn fi kan an ni pe o lọọ fipa ba ọmọ ọdun mẹrin kan lo pọ nile awọn obi rẹ lakooko ti awọn obi ọmọ ọhun ko si nile. Ohun to waa mu kọrọ naa buru ni pe arun ko gboogun wa lara ọkunrin yii, leyii to ṣee ṣe ko ti ko o ran ọmọ yii.

ALAROYE gbọ pe Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kejila, oṣu Keje, ọdun 2023 yii, ni wọn foju ọdaran ọhun bale-ẹjọ Magisireeti kan to wa lagbegbe Umuahia, niwaju Onidaajọ N Lekwa.

Oriṣii ẹsun iwa ọdaran meji ni wọn fi kan an. Akọkọ ni pe o fipa ja ibale ọmọ ọdun mẹrin kan. Ẹsun keji ni pe o tun ko aru kogboogun (HIV) ran ọmọ naa nitori pe Victor larun buruku naa lara tẹlẹ.

Ọlọpaa olupẹjọ, Ọgbẹni Okezuonu Obioma, to jẹ ọkan lara awọn oṣiṣẹ ẹka eto idajọ nipinlẹ naa to foju Victor bale-ẹjọ sọ fawọn oniroyin pe ẹsun mẹta ọtọọtọ loun fi kan an, ati pe gbogbo ẹri to foju han kedere loun ko wa siwaju adajọ naa, ko le rọrun daadaa fun un lati ṣedajọ to tọ fun olujẹjọ yii ni kia.

Afurasi ọdaran naa jẹwọ ni kootu, o ni loootọ loun larun kogboogun (HIV) tẹlẹ, ṣugbọn ti dọkita to n ṣetọju oun ti wo oun san.

Ọkunrin naa ni iṣẹ alagbaṣe pẹlu iṣẹ agbẹ loun n ṣe, ẹnikan toun jẹ ni gbese ẹgbẹrun mẹta Naira loun n wa lọ silẹ rẹ lagbegbe Ogbulafor, niluu Umuahia, lọjọ naa.

O ni, ‘Mo fẹẹ lọọ san gbese ẹgbẹrun mẹta Naira ti mo jẹ ni, nigba ti mi o ba obi awọn ọmọ ọhun nile ni mo pinnu lati tẹsẹ duro diẹ. Mo ba awọn ọmọ wẹwẹ kan ti wọn n ṣere lọwọ lakooko ti mo dele wọn. Ko pẹ lawọn ọmọde to n ṣere yii kuro nibẹ, ti wọn si fi ọmọ ọdun mẹrin naa silẹ, niṣe ni mo gbe e le itan mi lasan, ṣugbọn ti ọwọ mi ṣeeṣi kan an loju ara. Mi o ba a sun rara, ọwọ mi kan ṣeeṣi kan an loju abẹ lasan ni, idi ti ẹjẹ fi jade loju abẹ ọmọ ọhun si niyẹn. Bi mo ṣe ri i pe ẹjẹ n jade loju ara ọmọ ọhun ni mo ti gbe e silẹ ko maa ba tiẹ lọ’’.

Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, Adajọ N Lekwa ni  Victor jẹbi awọn ẹsun iwa ọdaran ti wọn fi kan an, ṣugbọn o sun igbẹjọ mi-in si ọjọ kọkanlelogun, oṣu Keje, ọdun yii.

Awọn aṣofin buwọ lu miliọnu lọna ẹgbẹrin dọla ($800m) ti Tinubu fẹẹ ya

Leave a Reply