Wahala ẹgbẹ PDP n le si i: Wike loun ko ni i fẹ, Atiku loun ko ni i gba

Ko jọ pe ipade alaafia ti awọn ma-jẹ-o-bajẹ inu ẹgbẹ PDP n sa gbogbo ọna lati ṣe ki alaafia le waye laarin Gomina ipinlẹ Rivers, Nyesom Wike ati oludije funpo aarẹ ninu ẹgbẹ PDP, Alaaji Abubakar Atiku, ti i kẹsẹ jari rara. Ohun to si foju han ni pe yoo pẹ diẹ ki wọn too ri ọrọ naa yanju nitori bi ọtun ṣe n sọ pe oun ko ni i fẹ, bẹẹ ni osi n sọ pe oun ko ni i gba. Bi ko ba si jẹ pe irin kan tẹ fun ọkan, ko sigba ti ko ni i di konko jabele, ti kaluku yoo si maa ṣe tirẹ.

Eyi ko sẹyin bi wọn ṣe ni Gomina Wike ṣe taku pe ko si ohun to le mu ki oun ṣe atilẹyin fun Atiku ju pe ko yọ Iyorchia Ayu to jẹ alaga ẹgbẹ naa kuro, o ni ti eleyii ko ba ṣee ṣe, a jẹ pe ki onikaluku maa lọ ni ilọ rẹ lo ku. Nnkan ẹyọ kan ti gomina ipinlẹ Rivers yii ti n tẹnumọ lati ọjọ yii wa niyi.

Ọrọ yii naa lo si tun ran mọnu l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ to kọja, nigba ti ipade alaafia kan tun waye laarin oun ati oludije funpo aarẹ fẹgbẹ wọn, Atiku Abubakar.

L’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ to kọja yii, ni ipade idakọnkọ mi-in tun waye laarin Atiku atawọn eeyan rẹ pẹlu Wike atawọn eeyan tiẹ naa niluu Abuja. Ohun kan naa ti Wike tun n tẹnu mọ nibi ipade ọhun ni pe afi ki Ayu lọ. O ni ti Ayu ba lọ nikan ni awọn le jokoo ajọsọ ọrọ, nitori bi alaga naa ko ba kuro nipo, awọn agbegbe kan wa ti ko ni i le de lati sọ pe oun n polongo ibo fun ẹgbẹ PDP, ti ipolongo ba bẹrẹ daadaa.

Yatọ si eyi, Wike ni yiyọ Ayu kuro nipo alaga lo le fi ẹgbẹ naa han bii ẹgbẹ to ro tẹlomi-in mọ tiẹ, to si n ṣe ohun to tọ ati eyi to yẹ. O ni lai si eleyii, ko si ọrọ kan ti oun fẹẹ ba ẹnikẹni sọ.

Ṣugbọn oludije funpo aarẹ lẹgbẹ PDP, Atiku Abubakar, naa ni ko si ninu agbara oun lati yọ alaga naa nipo. O ni ofin ẹgbẹ nikan lo le yọ ọ. Ati pe awọn ti ofin gba laaye lati yọ ọ ti jade pe awọn nigbagbọ ninu iṣejọba rẹ. Eyi lo mu ki ipade ti wọn ṣe lati wa alaafia ninu ẹgbẹ naa tun fori ṣanpọn, nitori ko sẹni to fẹẹ gba funra wọn.

Ki i ṣe Wike nikan lo n binu, bakan naa ni awọn agbaagba oloṣelu ọhun bii Oloye Bọde George, Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ṣeyi Makinde, Gomina ipinlẹ Benue, Samuel Ortom, Gomina ipinlẹ Abia, Okezie Ikpeaze, Enugu, Ifeanyi Ugwuanyi. Bẹẹ naa si ni gomina ipinlẹ Ondo, Ekiti, Plateau ati Cross River tẹlẹ, Oluṣẹgun Mimiko, Ayọ Fayoṣe, Jona Jang ati Donald Duke. Ọjọgbọn Jerry Gana atawọn mi-in bẹẹ naa fi aidunnu wọn han si bi Ayu ṣe wa nipo yii, wọn ni irẹjẹ ni, bi wọn ko ba si yanju rẹ, awọn ko ni i bọ sita polongo ibo fun Atiku, nitori ko si ohun ti awọn fẹẹ sọ fun awọn eeyan awọn tabi idi pataki kan lati ṣe bẹẹ nigba ti ọpọlọpọ awọn ipo to ṣe pataki ninu ẹgbẹ naa ti lọ sọdọ awọn eeyan apa Oke-Ọya.

Ẹyẹ ki i fi apa kan fo ni awọn Yoruba maa n sọ. Atiku nilo Wike atawọn eeyan rẹ ti wọn fariga pe awọn ko ni i ba a ṣe bi ko ba yọ Ayu nipo, bẹẹ ni awọn Wike naa nilo Atiku, nitori ti ọkunrin naa ba pada wọle pẹlu gbogbo idaamu ti wọn n ko o si yii, ko jọ pe yoo wo ibi ti wọn ba wa nigba ti wọn ba n pin ipo.

Ko ti i sẹni to mọ ibi ti ẹgbẹ PDP yoo gbe atẹ ọrọ naa ka bayii. Ṣugbọn kinni kan to daju ni pe bi wọn ko ba ri ọrọ naa yanju ti ibọ ọdun 2023 ba fi de, afaimọ ki wahala naa ma ṣakoba gidigidi fun wọn.

Leave a Reply