Ibrahim Alagunmu Ilọrin
“Ko sibi ti wọn ti n ṣe ru ẹ ni gbogbo ilu Ilọrin, wọn n ṣe Isilaamu, wọn tun n ṣe ṣọọsi ninu mọsalasi, wọn tun n ṣẹbọ. Ilu yii ko ni i gba, baba wa ọba Ilọrin ko ni i gba, Imaamu agba Ilọrin ko ni i gba, Imaamu Ìmọ̀le ko ni i gba, ki wọn ma jẹ ki a pada wa, wọn le ni awọn ni awọn ni ilẹ awọn, ṣugbọn ọba Ilọrin lo nilẹ. A o ba tija wa, ṣugbọn a o fẹẹ gbọ ohun to jọ bẹẹ mọ, ki i ṣe pe a daa labaa kọ, a pa a laṣẹ ni.
Eyi lawọn ọrọ ikilọ kọmbọki, to n ja bọ latẹnu Imaamu agbegbe Ọja tuntun, atawọn aafaa ẹlẹgbẹ rẹ mi-in lọsan-an Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ keji, oṣu Karun-un, ọdun 2024 yii, nigba ti wọn lọọ ya bo ile Alaaja Akankẹ more blessing Atayese, niluu Alálùbọ́sà, nipinlẹ Kwara, ti wọn fẹsun kan pe o n ṣe ẹṣin mẹta-lọkan.
Wọn lawọn waa ṣekilọ fun iya naa ni, tori ilu Ilọrin ki i ṣe ilu teeyan ti le maa ṣe ẹsin mẹta-lọkan, wọn ni imọlẹ ati imọ ni wọn fi tẹ ilu naa do, ẹsin Islam si ni.
Wọn tun sọ pe ẹni kan o le sọ pe oun fẹẹ jẹun, ko waa ba ilu jẹ, awọn ko ni i gba, to ba jẹ Islaam lo fẹẹ maa se, ko maa ṣe e, to ba si jẹ pe Kirisitẹni ni, ko tete maa ṣe e, ṣugbọn ko gbọdọ da ẹṣin mejeeji pọ mọ.