Wahala n bọ o: Ẹgbẹ Oniṣẹṣe laago ikilọ fun Ẹmia Ilọrin

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Awọn ẹgbẹ onisẹse nipinlẹ Kwara (ARSADIC), ti kilọ fun Ẹmia ilu Ilọrin, Alaaji Ibrahim Zulu-Gambari, atawọn aafaa ilu naa pe ki wọn dẹkun  idunkooko tabi pe ede abuku si awọn Oniṣẹṣe nipinlẹ ọhun, wọn ni gbogbo ọna lawọn yoo fi daabo bo igbagbọ awọn.

Ninu atẹjade kan ti Aarẹ ẹgbẹ Oniṣẹṣe Kwara, Dokita Ifagbenuṣọla Atanda, fi lede lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹwaa, oṣu Keje yii, lo ti sọrọ lori bi awọn aafaa kan niluu Ilọrin ṣe lọọ dunkooko mọ Yeye Ajeṣikẹmi Ọmọlara nile rẹ lori ẹsun pe o fẹẹ ṣajọdun ẹsin to nigbagbọ si, iyẹn iṣẹṣe, ti wọn si ni ko gbọdọ ṣe e. O ni ẹgbẹ Oniṣẹse nipinlẹ Kwara, labẹ ARSADIC, bẹnu atẹ lu idunkooko naa, ki awọn Musulumi nipinlẹ naa si dẹkun ṣiṣe akọlu si awọn ọmọ ẹgbẹ awọn nipinlẹ naa. Atanda ni ko bojumu bi ẹgbẹ awọn Musulumi kan ti wọn n pe ni Majlisu Shababa li Ulamahu, niluu Ilọrin, ati Agbẹnusọ fun Ẹmia Ilọrin, Abdulazeez Arowona, ṣe n halẹ mọ Yeye Ajeṣikẹmi pe ko gbọdọ ṣe ọdun iṣẹṣe to fẹẹ ṣe niluu Ilọrin.

O ni, “Nigba to jẹ pe awa ẹlẹsin iṣẹṣe mọ aaye wa, a o le maa ṣakọlu sawọn ẹlẹsin miiran, aa ni i faaye gba igbiyanju awọn kan lati fi ominira ti a ni lori ẹṣin ati ẹgbẹ dun wa bo ṣe wa ninu iwe ofin Naijiria.

” A o le kawọ gbera kawọn kan maa fẹtọ ti Ọlọrun fun wa ati eyi ti ofin Naijiria ṣatilẹyin fun, ti a si mọ pe Ilọrin, ipinlẹ Kwara,  jẹ ọkan lara Naijiria, a ti ṣetan lati daabo bo igbagbọ wa.

O tẹsiwaju pe ẹgbẹ wa lẹyin Yeye Ajeṣikẹmi Ọmolara bii ike ni, nitori pe ẹṣin awọn lo n sin, ẹsin yii naa lo si so awọn papọ. Ohun ti ẹṣin naa kọ awọn ni jijẹ mimọ, ki awọn maa bọwọ fun ofin, kawọn gba ẹlẹsin miiran laaye, ki wọn si pataki ọmọniyan, fun idi eyi, awọn o ni i laju silẹ ki ẹgbẹ kan tabi ẹni kan maa dunkooko tabi dẹruba ọmọ ẹgbẹ awọn’’.

Atanda rọ ijọba Kwara, labẹ iṣejọba Gomina Abdulraman AbdulRazaq, atawọn ẹṣọ alaabo ki wọn tete dide sọrọ naa lati daabo bo ẹmi ati dukia pẹlu ilana ofin bi iṣẹ wọn ṣe gbe e kalẹ.

 

Leave a Reply