Wahala n bọ o! Wọn lawọn kan fẹẹ pa Arẹgbẹṣọla l’Ọṣun

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Igun kan ninu ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC), nipinlẹ Ọṣun, ti wọn pe ni Omoluabi Progressives Caucus, ti kegbajare sita lori ọrọ kan ti wọn ni Kọmreedi Ismail Omipidan sọ laipẹ yii.

Ọmọluabi Progressives Caucus ke si awọn ẹṣọ alaabo lorileede yii lati ma ṣe fọwọ kekere mu ọrọ ẹni to jẹ agbẹnusọ fun gomina ana ọhun, Alhaji Gboyega Oyetọla, nitori ohun to ni i ṣe pẹlu ẹmi ni.

Alukoro fun ẹgbẹ naa, Abọsẹde Oluwaṣeun,  ṣalaye pe o han kedere ninu atẹjade kan ti Omipidan fi sita laipẹ yii pe wọn ti n gbero lati ṣejamba fun Ọgbẹni Arẹgbẹṣọla, yoo si lewu ki awọn laju silẹ ki ohunkohun ṣẹlẹ si ọkunrin oloṣelu to jẹ ogo ipinlẹ Ọṣun naa.

Ọrọ ti Omipidan sọ ọhun, gẹgẹ bi Abọsẹde ṣe fi sita ni pe, “Sibẹ, pẹlu ero ijọra-ẹni-loju, o n tẹsiwaju lati gbogun ti agbajọwọ to gbe ẹ jade si gbangba. Ṣugbọn ẹ jẹ ki n sọ ọ lẹẹkan si i pe ti Arẹgbẹṣọla ba n tẹsiwaju ninu ogun oṣelu to n ba ẹgbẹ atawọn to sọ ọ deeyan ninu oṣelu ja, o le ma ṣee ṣe fun un lati ye e (Survive it)”

Abọsẹde fi kun ọrọ rẹ pe ohun to jade latọdọ Omipidan yii mu ifura lọwọ pupọ, ko si ṣe e fi ọwọ yẹpẹrẹ mu latari gbogbo ikọlu ti awọn eeyan yii ti n ṣe si Arẹgbẹṣọla latẹyinwa nigbakuugba to ba wa sipinlẹ Ọṣun.

O ni ẹẹmeji ọtọọtọ ni awọn agbebọn ti ṣekọlu si ile ipolongo ibo Arẹgbẹṣọla ti wọn pe ni Ọranmiyan House, bẹẹ si ni ori ko o yọ nigba ti awọn agbanipa dena de e lọna Orisunmbare, niluu Oṣogbo, lọdun 2022.

O ni, ‘’Iwa ọdaran ni gbigba ẹmi ẹnikeji, Omipidan atawọn ti wọn wa lẹyin rẹ ti sọ ara wọn di ọlọrun nipinlẹ Ọṣun, oniruuru iwa ibi lo si kun ọwọ wọn, nitori naa, a n ke si awọn ẹṣọ alaabo lati gbe igbesẹ to wa nilana ofin lori ọrọ yii’’

Nigba to n fun Ọmọluabi Progressives Caucus lesi, Kọmreedi Ismail Omipidan sọ pe o yẹ ki awọn eeyan yẹ ọpọlọ Abọsẹde to gbe atẹjade naa sita ati tawọn ti wọn jọ kọ ọ wo daadaa.

Omipidan ni oun ko ni itan wahala nibikibi, bawo waa ni ẹnikẹni ti ọpọlọ rẹ pe yoo ṣe sọ pe oun fẹẹ pa odidi ẹni to ti ṣe gomina ati minisita ri.

O ni ṣe ni wọn kan n wa atamọ-mọ-atamọ lati pe oun lorukọ ti oun ko jẹ, nitori wọn mọ pe irọ patapata ni wọn n pa mọ oun nipa ṣiṣi ọrọ oun tumọ, ati pe ko sẹni ti ko mọ awọn ti wọn ni itan iwa jagidijagan nipinlẹ Ọṣun.

Leave a Reply