Florence Babaṣọla
Ile-ẹjọ Majisreeti kan niluu Oṣogbo ti dajọ pe ki awọn ọkunrin mẹta kan lọ maa naju lọgba ewọn lori ẹsun biba Sẹkiteriati ijọba ibilẹ Ẹgbẹdọrẹ to wa niluu Ido-Ọṣun, nipinlẹ Ọṣun jẹ.
Awọn olujẹjọ naa ni Idowu Wasiu, ẹni ọdun mẹrinlelogun, Adekunle Adewale, ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn ati Adewunmi Damilọla, ẹni ọgbọn ọdun.
Fatọba Temitọpẹ to jẹ agbefọba lori ọrọ naa ṣalaye pe aago mẹsan-an aabọ aarọ ọjọ kẹrinlelogun, oṣu kẹwaa, ọdun yii, ni wọn huwa naa.
Fatọba sọ pe ṣe lawọn olujẹjọ naa mọ ọn mọ ba geeti, ferese ati ilẹkun sẹkiteriati naa jẹ, eleyii to nijiya labẹ ipin aadọrin abala ikẹrinlelọgbọn ofin iwa ọdaran ipinlẹ Ọṣun.
Lẹyin ti wọn sọ pe awọn ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan wọn ni agbẹjọro wọn, Akinwumi Babatunde, bẹbẹ fun beeli wọn lọna irọrun.
Adajọ Adijat Ọlọyade paṣẹ pe ki wọn lọọ fi awọn mẹtẹẹta pamọ ṣogba ẹwọn ilu Ileṣa titi di ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu kọkanla, ọdun yii, tigbẹẹjọ yoo tun waye lori ọrọ wọn.